Smiley face

Ogota Eniyan Ku, Ogorun Wa Loju Iku Nibi Ado Oloro Onibeji To Dun Ni Maiduguri Lana

Nnkan bi ago mokanla koja ogun iseju ni awon ado oloro onibeji kan dun ninu oja Maiduguri ni Ipinle Borno lana (25-11-14) nibi ti awon eniyan bi ogota (60) ti fo petepete kale bi eyin nigba ti awon eniyan bi ogorun (100) wa ni ese kan aye, ese kan orun alakeji.

University of Maiduguri Teaching Hospital ni ile iwosan ti won ko awon oku naa lo nikete ti isele naa waye. Igba ti ibe kun ti ko le gba awon oku mo ni won bere si ni gbe awon oku lo si State Specialist Hospital.

Gege bi a se gbo, omobirin to je iranse Boko Haram kan to gbe ado oloro naa sabe aso lo rin wo aarin ero ko to di wi pe o sana si ado oloro naa ti oun ati gbogbo ero to wa layika si doku loju ese bi igba ti Sango ba ja.

Nibi ti awon eniyan ti n saajo awon eniyan to ku ati awon ti won farapa ni ado oloro mii tun dun lara omo Boko Haram mii ti gbogbo awon ara oja si se bee di oku leleja n ta.

E je ka gbo ohun ti okan lara omo Ologun Naijeria wi nipa omobirin iranse Boko Haram to dana iku saaju:

"killing herself and some traders and their customers who were near her."

"Just as people gathered around her
corpse and few other people that died in the first explosion, the male bomber detonated the explosive on him.

No one can give you the exact casualty now but over 50 people were
killed and many have been rushed to hospital."

E je ka gbo nnkan ti Ali Bukar to je okan lara awon babalaje inu oja naa so:

"They were two suicide bombers. The first detonated an IED, killing herself and many people.

But as traders and their customers were running for their lives, the other bomber detonated his own, killing many more.

I saw about 14 tricycles evacuating corpses to the hospital."

Awon omo ologun ko faye gba awon oniroyin lati ya aworan ibi isele naa. Oniroyin ojumilose kan to gbiyanju lati ya awon aworan naa pada jeyan re nisu lodo awon soja nibi ti won ti na oniroyin naa bi ole.

Boya eyin ko ri akole iroyin yii ka, ohun ti akole so ni wi pe: Ogota Eniyan Ku, Ogorun Wa Loju Iku Nibi Ado Oloro Onibeji To Dun Ni Maiduguri Lana Ojo Isegun.

Awon ota n gbogun sugbon Naija ni o pada segun.

E ku asiko yii!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment