Smiley face

Morufa Eko 3: Igbin Oko Anti Mi Ti Fenu Kanyo, O Di Dandan Ko Ku



E ku deede asiko yii gbogbo dukaduaka. Mo si fe fi asiko yii ki gbogbo musulumi aye wi pe won ku awe Ramanda tuntun to wole de. Emi wa yoo sika re lagbara Oluwa oba. Leta Morufa Kini ti wole, Leta Morufa Keji ti dori ate, Leta keta ni yii. Mo tun ki yin kaabo leekan si lori itan igbesi aye Morufa Eko ti a ti n baa bo. O ya, e je ka lo ka leta tuntun naa.

Sii Oniroyin,
Mo ti so fun yin bi mo se rin irinajo mi de ilu Eko lodo anti mi. Bakan naa ni mo ti so ninu leta mi to koja bi oko anti mi se fi tipatipa ba mi lajosepo. Mo n tesiwaju ninu leta mi yii. E ku amojuba mi.

Opolopo yoo maa ro idi ti mo fi n tu igbesi aye mi han si araye ri. Akoko na, awon Yoruba ni ogbon ologbon ni kii je ka pe agba ni were. Eni to si jin si koto, o ko arayoku logbon ni. Aimoye isele lo sele si mi laye to maa n ba mi lokan je nigba ti mo ba boju weyin; ti mo ba ranti. Igbagbo mi si ni wi pe ti mo ba so tokan mi jade, boya ti okan mi ba fuye, ara mi yoo ya gaga. Maa si ti ipa bee gbagbe awon ohun ateyinwa.

Mo tun gbagbo wi pe iriri mi yoo ko aimoye awon eniyan logbon gidi, idi ni yii ti mo fi n ko leta mi yii ranse si olootu.

Irisi oko anti mi ni a le fi we igiripa, o san-angun daada, gbogbo agbara to ni lo si fi n gun mi mole. O dabi igba ti paipu omi ero ja, ti won wa n ri suku agbado mo oju omi paipu to ja lati fi da omi naa duro.  Bee lo se ri lara mi bi oko anti mi se n ti ‘opa’ abe re si mi labe. O n ta mi bi igba eniyan fi ata soju, bee ni i dun mi bi eni wi pe obe ni won fi n ge eran ara mi. O ti faso bomi lenu tele, sugbon nigba to ya, o yo aso to fi bo mi lenu nigba to sakiyesi wi pe o ti re mi. Emi gan-an ko tile le pariwo mo, o ti pe ju, kii se leyin igba to ti wole si mi lara tan. Mo kan gbin kin sinu lasan ni, ti mo n lora, omije si n san gba ereke mi bo si ipako.   

Igba to se ohun to fe se tan, o dide. O si bere si ni be mi wi pe ki n ma binu wi pe ise esu ni. O ni oun ko tile mo oun to sele si oun ti o oun fi wu iru iwa bee. Mo si wa lori beedi, mo n sunkun. Okan mi kun fun ibanuje. O kunle lori ese re mejeeji, o n bemi. Sugbon iru ebe wo gan-an lo n be mi leyin to ti se ohun to fe se. Mo Joko sori beedi, mo si n wo bo ti n bemi wi pe ki n ma binu wi pe asise ni.  Ninu okan mi, ko si iru ebe to le bemi, dandan ni maa gbesan iya to fi je mi. 

Mo dide lo si baluwe, mo tun ara mi se, mo si jade lo mu omo anti mi ni ile iwe lai ba so ohunkohun. Sugbon mi o le rin daada. Ti eniyan ba se akiyesi mi, yoo ri daju mi wi pe mo n ketan rin, o si dabi eni wi pe mo gandi sita die ju ti tele lo. Emi ga-an o gbadun ara mi ninu. Bi mo se n lo ni mo n ronu iya ti mo le fi je oko anti mi. Oteyii ni yoo gba wi pe ehin mu jabe lo. Ti Sango ba n pa araba ti n fa iroko ya, bi tigi nla ko. Ojo ti sigidi fe sere ete loni ki won gbe ohun we ninu ojo. Ojo ti igbin ba ti fenu kan iyo, ojo naa lo raye mo. Omode bu igi iroko o boju weyin, se oojo ni Oluwere n pa ni? 

 Omo anti mi nikan lo seku ni ile iwe, tisa re binu wi pe o pe ki n to wa mu, mo ni ko ma binu. Igba ti mo mu omo yii de iso anti mi, o bere idi ti mo fi pe. Mo paro wi pe okada lo kolumi lateyin. Mo ni awon kan ni won saajo mi, won ni ki n simi die. Nitori bi olokada naa se gba mi ko duro rara. Mo fi oogun arariro ti mo ra lona han-an. O ni see maa ma lo sile lati lo si mi. Mo ni rara, ko je n wa ibi kan fehin le si, boya ti mo ba tun sinmi die ara mi o na die sii.

Anti mi bere si ni fun olokada naa lepe, o ni sisesise yoo ba olokada naa nibi ti won yoo ti fi nnkan buruku kan-an. Nibi ti mo joko si, mo si n ro wi pe sisesise naa si ti de ba oko anti mi, asiko yii ni emi naa yoo si daju re dele. Kosi eni to le bemi ti mo le gbo, ko si ohun to le wi  ti mo fi le darijin. Oro ma soko, sugbon eyi ti mo mu dani yii di dandan ko sole sile odaju eniyan to fi tipatipa ba mi lajosepo.

Ninu leta mi to n bo ni e ti gbe ri ekunrere alaye. Iwaju-iwaju ni opa ebiti n re si, Olayemi Oniroyin, iwaju loo maa lo. O seun mi gan-an. Ire
    
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment