Smiley face

Morufa Eko 4: Mo Ti Ra Majele Ti Mo Fe Fi Pa Oko Anti Mi

Ohun akoko to ko koko wa si mi lokan ni majele. Boya ki n fi majele si inu onje re. Sebi iku ni ere ese. Ika to ba se loba n ge. Ti eera ba fini pegi, eniyan an won danu ni. 


Ti adiye ba dami loogun nu, ti mo ba fo leyin je ko leewo. Sugbon eru iku n ba mi. Ti mo ba fi majele sinu onje re to ba ku se ko ni leyin fun mi? 

Mo si le fi majele sinu onje fun ki n salo, sebi emi naa ti mo Eko die; mo si mo ibi ti mo le sagba lo. Sugbon sisalo gan-an ni o je ki asiri mi tete tu wi pe emi ni mo seku pa oko anti mi.
Iru ipo wo ni anti mi yoo wa pelu omo re ti mo ba seku pa oko re. Awon ero orisirisi lo n wa si mi lokan. 

Awon ero yii si n mu eru ba mi gidigidi. Ti mo ba ni ki n wo didun ifon, se mi o ni hora deegun bayii?
Ti a ba ni bi ejo segun to ni i se dana re, aifaimo ki n ma tina bole. Sugbon okan mi kun fun ogbe ati edun okan, se iya naa yoo wa je mi gbe ni? 

Ko wu mi ki n darijin rara, ti mo ba gbesan ni okan mi yoo to fuye. Eyi lo mu mi tesiwaju lati maa wa majele ti mo le fi sinu oje fun-un. 

Mo ki eyin oluka itan igbe aye mi kaabo leekan si. Boya igba akoko tie yin ba mi pade ni yii. Oruko mi ni Morufa Yekeeni. Igba kerin si ni yii ti n maa fi leta mi ranse si olootu OlayemiOniroyin.Com. Maa ro yin lati ka Leta Mi Kinni (1st), Leta Mi Keji (2nd), ati Lata Mi Keta (3rd) ki e to maa tesiwaju lati maa ka eleyii ti mo n ba bo yii. 

Sebi asoti oro ni i je omo mi gbena. Ona ti o soju eni su, a maa nira lati gba ti okunkun ba su bole. Titi laelae ni i si maa fi imoore mi han si olootu Olayemi Oniroyin fun anfaani la ti tete pepe Morufa Eko lori ikanni won. E se o. 

O ya, e je n pada si ori alaye mi.
Ati ri majele kii se ohun to nira fun mi rara. Awon omo oloko ni garaji la n taja fun ju. Kini eniyan si n wa lowo awon omo oloko ti ko si? 

Ogun buruku orisiirisii lo wa lowo won. Koda, ibon mbe lowo won pelu. Ati ri iru nnkan bee gba lowo won ko ye ko nira fun mi. Iro kekere kan pere ni mo ni lati pa, boya, ati seinji die lowo. Sebi enu ofifo kii dun yanmuyanmu. 

Oko anti mi ko dekun ati maa be mi ni koro, gbogbo igba ni i fi owo bemi, a tun ra aso fun mi. Sugbon ko si eyi ti mo gba lowo re. Ko si yee so wi pe oun nife mi denudenu, ati wi pe oun setan ati femi ti mo ba le se toun. 

Esi ti mo fun lojo to soro naa jade ni yii: 

"E setan lati femi? Iru oro wo le n so lenu gan-an naa? Nje e mo bi mo ti je si iyawo yin? Oran tee da sile e o ti tan, o tun ti n pete omiiran. 

Mo sese gba wi pe agbaaya oponu ni o, afofungbemu, oloorun, alailojuti, ayirada, oloriburuku, olosi, eniiya, eni aijiiri-aijiiko, akindanidani, oninubibu, olopolo dudu, eniyan jatijati eranko lasan ekeji aja."

Inu bi mi, mo si fi ibinu soro buruku si oko anti mi. Sugbon nigba to ba ku emi nikan, ekun ni maa tun bu si peregede. Igba to ya, mo n ro bi eni wi pe ki n salaye ohun to sele naa fun anti mi. Sugbon, eru n ba mi. 

Ki won maa lo yii oro naa le mi lori. Won a ni kilode ti mi o pariwo faye lojo ti isele naa sele. Abi ki n pada si ilu Ibadan ni. Sebi ti iwaju o ba se lo, eyin a se pada si. Ti Eko o ba se e gbe fun mi maa si pada silu Ibadan nibi mo ti wa.

Lenu igba ti mo de ilu eko yii, mo ti ni oko afesona ninu awon omo oloko ti oruko re n je Santana. Mi o tile mo idi ti mo fi gba fun omokunrin naa, werewere re po; o ti le soro ju. 

Sugbon, a maa nawo fun mi, o si je n nnkan to je ki n nife re daada. Sugbon mi o ti fe so ohun kohun nipa ife emi ati Santana bayii. Santana ti so fun mi ri nigba kan seyin ni wi pe baba kan mbe ni Ojuelegba (mi o fe daruko baba naa nibi) ti mo n ta oruka aluwo ati orisiirisii ogun bi onde, oruka ija ati bee bee lo fun awon eniyan. 

O ni gbogbo igba ti ija be fe sele ni garaji Oshodi, ibe ni awon ti ma n dira ogun ija. O ni baba naa tun mo nipa gbere okigbe ati ayeta ati awon ogun isora mii. Mo ro wi pe ti mo ba le dogbon beere bi mo se le ri baba naa, odaju wi pe yoo ni iru majele ti mo n wa. Bi ogbon bi awada, mo wadii nipa baba naa lowo Santana. O juwe ibe fun mi, mo si wa ibe kan. 
 
Okunrin naa kii se agbalagba rara, boya yoo ku die ti yoo fi to nnkan bi omo ogoji odun. Igba ti mo de ibe, eru tile n ba mi boya okunrin naa ko ni fun mi ni ohun ti mo fe. 

Boya yoo maa bere ohun ti mo fe fi se. Igba ti mo salaye iru majele ti mo fe, ko tile jo okunrin naa lo ju. Kosi beere idi ti mo fi fe lo. 

O dabi eni wi pe oju tie gan-an ti da. Eniyan ti ko ba si loogun arinya, kii je aayan.
Okunrin naa ko tile beru ti gbogbo re ba yiwo, ti won ba fi olopa mumi, ti emi naa si n mu awon olopa naa bo lodo re. Ta lo mo? 


Jagunlabi ti le lo se ogun asegbe. Ohun ti agbalagba fi n jeko, abe ewe lowa.
Eniyan ti o ba sowo ale, yoo leni ibusun. Eni ti o si besu jeun, sibi re yoo gun daada.

O ti ni awon ogun naa nile, Olorun nikan lo si mo iye eniyan to ti taa fun.
Iru majele ti mo beere kii se majele oju-ese, ti eniyan ba je majele naa, yoo to nnkan bi wakati mejila tabi ju bee lo ko to le bere ise. Mo ra majele naa, mo si gba ona temi lo. 


A ti lo majele naa ko nira rara, lubulubu bi atike lori, mo le gbon sinu onje tabi inu otin. Kete to ba si ti de inu onje tabi otin ni yoo pare mo ohunkohun ti mo ba da sii lai mu ifura dani.


Anti mi ti je ki n mo wi pe ohun fe lo si ilu Ibadan gege bo ti mo n lo to ba di ale Satide. Gbogbo Sunday, owo mi lo wa. 

Aye o si gba mi lati sise owo mi bi mo ti fe. Ti mo bata 'were' lofa lale ojo Sande, ki ina to dahun yoo di bi osan ojo Monday kosi seni to le fura si mi rara.
A je wi pe ipade di Sande nu-un.

Kilo wa sele lale ojo Sunday nigba to ku emi ati oko anti mi sile?

E o ni binu si mi ni, won ti fun mi ni gbedeke iye oro ti mo le te jade leekan soso ko ma ba tabuku ewa ikanni yii ni. Sugbon mo fi dayin loju wi pe ko ni pe rara tie o tun fi ri owo mi.
Oniyan se e, olobe se e. Eyin te e ba wa fi ife je pata ni mo ki, ajose wa ko ni baje. Amin

Emi ni tiyin ni tooto,
Morufa Yekeeni































Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment