Smiley face

Bayii Ni E Se Le Mo Ojulowo Saja Ti Ma n Saaji Foonu Ni Kiakia

Orisirisi saja foonu lo wa, awon saja foonu kan wa to je wi pe bee ba fi saaji foonu fun bi wakati meji, okan eniyan o ti bale wi pe o ye ki batiri foonu naa ti gba opolopo agbara, sugbon nigba ti eniyan o ba fi ye foonu naa wo, eniyan yoo wa 'disaponinteedi' bi Gbajabiamila. Foonu naa yoo dabi igba ti eniyan ko saaji re rara.


Sugbon awon saja foonu kan wa, Saraki ni won. Ti eniyan ba ti iru saja bee bona, kiakia ni foonu yin yoo gba opolopo agbara laaarin iseju perete lai fi asiko sofo rara.


Nibayii, mo fe se alaye bi eniyan se le da Saraki mo, saja foonu to n gba agbara ni kiakia ati Gbajabiamila, saja foonu ti kii tete ri agbara gba ni kiakia.

Awon Yoruba si bo, won ni ti eniyan ba pe lori imi eesinkeesi ni ka ni mo be. Se e mo wi pe ti foonu ba pe ko to saaji, awon onise monamona ile Nigeria le se bee se monamona.

Sodiafoo, eniyan gbodo maa se amulo saja foonu to ja fafa.

E mu saja foonu yin ki e wo ara re, e ri awon orisi nomba kan lara re.

Ikinni ni ina to wole: In-put
Ekeji ni ina to jade: out-put

Labe ina to jade, Out-put, ti e ba ri nomba yii 5V----1A tabi 5V----1000mA tabi nomba to ba kere si 1000mA eyi tun mu si wi pe Gbajabiamila ni saja foonu yen, ko mo bi won se n gba agbara ni kiakia. Iru awon saja bee ko se e gbemi le, o maa pada jayin kule ni.

Sugbon sa, ti nomba agbara ina to jade ninu saja yin ba je 5V----2A tabi 5V----2000mA tabi eyi ti nomba re tun ju 2000mA lo, e gba wi pe Saraki le mu dani. Iru awon saja bee mo agbara gba ni kiakia fun foonu yin.

Ibi ni maa ti duro, @OlayemiOniroyin loju opo mi lori twitter. E pade mi fun akotun iroyin isele to n lo lowo.

Ka pade layo!
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment