Aba ti Ile ise ijoba apapo mu de iwaju Aare Muhammadu Buhari lati ra awon oko oloju ina ija ti owo eyokan re je irinwo milionu (400M) fun lilo PMB ni Buhari ti wogi le bayii. Won ni anfaani awon oko yii ni lati maa daabo bo baba eni odun mejilelaadorin (72yrs).
Sugbon Buhari ni fifi owo ilu sofo gbaa ni oun ri igbese naa si. O ni awon oko ti Aare ana, GEJ, loku si see lo fun oun gege bi Aare.
Agbenuso fun Aare leka iroyin, Garba Shehu si ti jeri si iroyin naa wi pe Buhari ti ko lati gba ki won ra oko irinwo milionu fun igbadun Aare ile Nigeria nikan.
Odun 1942 ni won bi Aare muhammadu Buhari si ilu Daura to wa ni Ipinle Kastina. Oun si ni omo eleeketalelogun (23rd) omo ti baba re bi. Ati igba to si ti wa lomo odun merin ni baba re ti fi ile aye sile. Iya re lo si n toju re lati igba naa wa. Igba meta otooto ni Buhari ti feyin janle nipa igbiyanju re lati di Aare ile Nigeria. Ninu eto idibo odun 2015 to gbe Buhari wole, awon egbe alatako fesun kan Baba Zarah wi pe ko ni sabuke. Titi di akoko yii, ko ti si eni to le so nipato boya looto ni Baba Yusufu ni sabuke tabi ko ni sabuke.
@OlayemiOniroyin, eniyan ti o la laye, aimoye isubu ni yoo ri. Eni naa si gbodo je olokan lile lati koju isoro aye. Lafikun, e ma se pon iro lewe, bopeboya otito ni yoo leke.
Ire o!
Home / Uncategories / Buhari Ti Tako Aba Ile Ise Ijoba Lati Ra Oko Irinwo Milionu Naira (400M) Fun Ilo Aare Ile Naijeria
Subscribe to:
Post Comments
(
Atom
)
0 comments:
Post a Comment