Awon Yoruba nibi taa roko ti si, ibe naa laa fabo si. Morufa Eko ti pada gbe itan igbesi aye re nibi to ba de ninu leta to ko koja. Leta eleekarun-un ni yii ninu awon leta ti Morufa ti n ko ranse si wa. E je n kin danu duro nibi naa ke e le gbo tenu Morufa.
Sii Olayemi Oniroyin,
E tun ku amojuba mi leekan sii.
Anti mi ti gbera lo si ilu Ibadan lale ojo Satide pelu omo re gege bo ti wi fun mi.
O ti wa ku emi ati amugbalegbe re ati omo Tapa kekere ti n ba wa fabo. Sugbon nipa ti itoju ile, owo mi ni gbogbo re wa.
Emi a ti ore mi kan wa ti emi ati e ti ni adehun wipe mo ni oro kan ti mo fe so fun-un. Ore mi yii n ta ate, ninu Oja Oshodi kan naa la si jo wa. Mo pinnu lati salaye oro naa fun, boya o le ni amoran kan lati gba mi. Ni ale ojo Satide ti anti mi lo si ilu Ibadan, leyin taa palemo ka to lo sile lajo soro wa.
Amoran to koko gba mi ni lati ma so oro naa fun anti mi. Emi gan-an ko tile ni lokan mo lati wi fun won.
Eekeji, o ni ti ibe ko ba wu mi mo, mo le ko jade kuro nile fun won. (Mi o salaye mi dele fun ore mi wi pe mo ti setan ninu okan mi lati seku pa oko anti mi). Ohun ti mo wi fun ni wi pe isele naa dun mi deegun, ti mo ba si reni ba mi gbesan inu mi i ba dun.
Omo igboro ni Tolani ore mi, oju re si ti re ju temi lo. Igba to ya, o tun yii oro re pada. O ni ti oko anti mi ba fe femi, kilode ti mi o le fe ki n maa gba owo (money) owo (hand) re. O ni sebi o ku lowo lowo, odindi maalu nla ni mo on pa lojo kan, o tun maa n pin eran fun awon alapata egbe re.
O ni ki oko anti mi o gbale fun mi nita, ki n si maa gba owo owo re. O ni ti mo ba le ri owo gidi gba lowo re , sebi enu ki emi naa daduro ni.
To ba si wu mi, mo le maa fe e lo. Ko si tuntun labe orun mo. A ri iru eleyii ri, eru la fi n da ba oloro.
Ti o ba si wu mi, ki n ja danu, ki n wa eloomi fe. Owo ni koko!
"Morufa, Eko lawa yii o; Eko wenjele! O ri ese were n le o bu, ologbon wo ni o gbe tie duro. O n pariwo oko antin re ni, se baba ati iya kan naa lo bi eyin mejeeji ni. So fun wi pe ko ba o wa owo gidi, kofi si soobu, ko gba ile fun o, ko si ko kuro nibi ti anti re wa. Lo ba pari."
Tolani ko si ni ile oko mo. Omo kan to si n to lowo ko le so pato eni to bi fun. Eni to gba omo naa gege bi baba, korikansekan lo fi gba lati je baba omo naa. Tolani lo n bo omokunrin naa, oun naa lo si n ra aso si lorun.
O dabi e ni wi pe ounje ti Tolani fun okunrin naa je lo je ko gba lati je baba omo naa. Orisirisi orekunrin lo si wa lowo re eleyii ti oko re mo si sugbon ti o gbodo soro. Okunrin naa suegbe pupo, o ku le je wi pe ogun ni Tolani n lo fun.
Bawo ni okurin mii yoo se ma ba iyawo eni serepa fifi owo gba-ni-nidi loju oko iyawo lai se wi pe oju re fo.
Bi o tile je wi pe emi naa ti se awon asise kan nigba kan ri, nigba ti mo wa ni ilu Ibadan. Sugbon ko tun wu mi ki n pada si igbe aye mi atijo.
Nibi irinkunrin ti mo ma n rin kaakiri, okunrin ti fun mi loyun ri to pada ko jale wi pe oun ko.
Okunrin naa salo ti mi o ri mo.
Eni ti mo n so yii, tisa ile iwe mi ni. Ogun ni mo lo lati fi se oyun naa, o yi mo mi lowo eleyii to so mi di ero osibitu.
Osu kan ati ose meji ni mo lo ni osibitu Oluyoro ki n to pada wale. Gbogbo oro ti awon obi mi so, ko si eyi to wo mi leti. Sebi aja ti o ba sonu, ko ni gbo fere olode. Omo ti obi ba si n bawi to n wa orun ki, o setan ti o parun ni.
A kii ni ki omode o ma dete, to ba ti le danu igbo gbe. Sugbon sa, aro ti n daran, orun elese meji ni i dasi.
Aimoye owo ni awon obi mi na ati aajo sise lati da emi mi pada wa saye.
Leyin ti ara mi ya tan, mo tun fo sita. Lojo odun aisun odun eegun kan ti won se ni awon okunrin bi meta tun fi tipatipa ba mi lajosepo.
Leyin ti ara mi ya tan, mo tun fo sita. Lojo odun aisun odun eegun kan ti won se ni awon okunrin bi meta tun fi tipatipa ba mi lajosepo.
Ati igba naa ni mo ti pinnu lati di atunbi. Opolopo awon nnkan to ti sele si mi koja yii, ti mo ba ro papo mo eyi ti oko anti mi tun se maa n je ibanuje okan nla fun mi.
Awon okunrin ti fi oju mi ri iku, omije ekun si ti jade loju mi, oju mi ti ri oran, o si ti ri ibanuje lowo awon okunrin. Ohun ti oko anti mi se gan-an le maa to ijiya ti mo pinnu lati fi dalola.
Sugbon ti mo ba ro gbogbo fitinati ti mo ti ba pade lowo awon okunrin, o n semi bi ki n gbesan re pada lara oko anti mi.
Ojo ti awon okunrin meta ba mi lajosepo, ohun ti won se fun mi ko se fenu so.
Ibanuje okan nla lo je fun mi eleyii ti mi o ni fe tenu bo alaye nipa re nibi nitori ohun ibanuje gbaa ni.
Maa si fi asiko yii ro ijoba apapo, ki won se ofin idajo iku fun enikeni ti o ba fi tipatipa ba obirin lajosepo. Boya nipa sise iru ofin yii, awon odaju, ika okunrin yoo dekun ati maa se awon obirin sakasaka.
Nibayii, majele ti wa lowo mi, amoran ti ore mi si gba mi wa lokan mi. E wo ni ki n muse ninu mejeeji? Ore mi fe ki n maa fe oko anti mi sugbon emi fe fun ni majele je ni.
Sugbon ohun to le dun mo mi ninu ju lo ni ki n lo Majele ti n be lowo mi. Eleyii yoo je bi ijiya fun ohun ti awon okunrin ti fi oju mi ri lati eyin wa.
Mo ti bu obe dani lati soobu lale ojo Satide ta a fi je ounje nile. Ojo weliweli ni mo ba wole. Igba to ya, ojo naa da sugbon otutu n mu, ategun si n fe yee.
Mo n gburo wi pe ara n san lati ona jinjin. Eleyii to dabi wi pe ojo naa si n ro lowo ni awon apa ibi kan to jinna. Ori ibusun ni mo wa, mo fi eyin lele; koju si oke aja.
Orisirisiri ero lo n wa si mi lokan. Mo n ro wi pe anti mi yoo ti de Ibadan tabi ko ku die fun lati wo ilu Ibadan.
Aago mewa sese fe lolu ni. Mo tun ranti oko anti mi ati ojo idajo re to ti pe lonii. Aya mi n so ki-ki-ki, eru si n ba mi. O dabi igba ti won so okan mi sinu koto to jin, to wa n lo laide isale.
Mo fowo kan apo otun jeans sokoto ti mo wo , mo ri wi pe majele naa si wa nibe. Bi aya mi ti wu ko ja ju bee lo, ale oni ni maa se idajo oko anti mi.
Amala dudu to gbona ni mo ro, emi ti jeun, omo Tapa kekere ti n ba wa fabo si ti sun. Emi wa ninu yara odo mi lori ibusun, mo ko oju mi soke mo n wo aja.
Oko anti mi ko ti wole de, mo n reti re ko de, ko de ko wa gba ojo iku re. Leyin ounje mi ale yii, boya yoo tun ni anfaani bi ounje meji si ko to dagbere faye. Kosi ni si eni ti o fura si ounje ti mo ba gbe fun, ibomii ni won o sebi ofa ti wa.
Okan mi tun bale die, nigba ti mo tun ranti wi pe majele ti mo fe lo kii se eyi ti n pani loju ese. Sugbon ohun to daju ni wi pe oko anti mi ko ni ba wa sun ninu ile yii lale ola.
Ko pe ni oko anti mi wole, bo se wole ni i pariwo "ebi n pami". Mo lo si yara idana, mo pese ounje re fun.
Mo bu obe ewedu sinu abo, mo bu ata le lori pelu eran meji. Mo mu amala re jade ninu kula pelu aso ti mo yi mo o lara. Mo tu aso naa, mo si bo amala naa kuro ninu ora, mo si sinu awo tangaran.
Mo se ounje naa lojo, mo si se gbogbo awon eto to ku ti mo fe se sii pata. Igba ti mo pari, mo gbe awon ounje naa si inu ike kan feregede pelu omi isinwo. Mo mi kanle doo, mo si pinnu lati tesiwaju pelu ero okan mi.
Oko anti mi gbadun ounje naa yato nitori wi pe gbogbo re pata loje tan lai ku nnkankan. O si le je ebi ti n pa lo mu pari gbogbo ounje naa.
Sugbon amala naa ko seku, o si la abo obe re ti gbogbo re si funfun bi eni wi pe won sese fo abo naa tan ni. O pe mi lati wa palemo, mo gbe abo wo yara idana mo si gba ibe wo yara mi lo.
Mo tilekun yara mi lateyin, mo sun gbalaja lori beedi gege bi mo ti se tele ki oko anti mi to o de. Okan mi ru, ibanuje gun ori emi mi, mo si bere si ni sunkun lai ri eni na mi legba.
Eyin ololufe Olayemi Oniroyin, ibi ni maa ti duro. Titi d igba ti maa tun fi pada wa, adura mi ni wi pe e ko ni rogun ibanuje ni sakani yin. Amin
Emi ni tiyin ni tooto,
Morufa Yekeeni ( Morufa Eko)
Morufa Yekeeni ( Morufa Eko)
0 comments:
Post a Comment