Smiley face

IBB Pe Omo Odun Merinlelaadorin (74) Leyin Ti MKO Abiola ati Dele Giwa Ti Lo

Leyin bi Ibrahim Badamasi Babangida se fagi le eto idibo June 12 odun 1993, aimoye ilu ni won ti gbe poosi IBB, awon kan woso odi lo soja lo gbe sepe, won ni Maradona o ni kije.

Odun mejilelogun ti koja bayii ti isele naa ti waye. Maradona ojosi si ti pe omo odun merinlelaadorin (74) lonii.


Ninu eto idibo odun 1993 eleyii ti gbogbo eniyan mo si JUNE 12, opo omo Naijeria lo gba wi pe "Emuke" Baba Kolawole lo wole, a fi eti gbo lasan ni Moshood Kasimawo Olawale Abiola o roye je.

O ri fitinati yii naa ni Aare Ona-Kaka-N-Fo ile Yoruba ku si, awon kan tile ni won pa a ni. Ibi eniyan o si sebi oba Yaradu wa nibe. Sugbon ta lo pa oko Kudi? To lo ran oko Simbi lo Sorun aremabo?


Akikanju oniroyin to gbona bi Dele Giwa o pe meji nigba aye re. Boya ni Jagunjagun bi Ogunmola tun le pada wa saye. Sebi owo tada mo naa ni kada lehin. Iku omi ni pa omuwe lodo.

IBB ni omo Giwa ti lenu ju, lo ba ku fi leta iku ranse si nile. Odun 1986 ni isele naa waye, boya ni mi o ni royin fun iran ti mbo leyin mi.

Ibrahim Badamasi Babangida mbe niluu Minna, ile funfun bi aafin oba ni i gbe. Mo tile gbo wi pe o feran eja tutu ni jije nigba o ba n gba afefe tutu leti omi. Kugu aye mbe loke, Baba gbe mi debe kiakia.

Awon kan tile ni Ogbomoso ni iran re ti wa. Awon kan lomo Yooba to so ara re di Gambari osan gangan nii se.

Eyi to wu ko je, ohun to pamo loju eniyan kedere ni niwaju Oluwa oba.

Ibrahin Babangida ni mo wa ki ku ori ire ojo ibi re to ko lonii.

Baba Muhammadu, Baba Aminu, Baba Aishatu, Baba Halimatu ni mo wa beri fun.

Bo o ba lo igba odun laye, odun kan pere ni won o fi ka fun o lode orun.

Ohun to dabi alaafia o si, ki Baba mimo ba mi fun o ni eyi to po ninu ifokanbale. Amin.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment