Smiley face

Morufa Eko 11: Gbogbo Ara Ile N Wa Mi, Won O Mo Ibi Ti Mo Wa

Sii Olayemi Oniroyin,

Mo tun ki yin ku asiko yii eyin ololufe wa. Awon Yoruba ni ti ina ko ba tan laso eje kii tan leekanna.

Se o gbagbe ohun ti mo wi ninu leta mi ti mo ko gbeyin. Mo so fun yin wi pe awon alaye mi to ku ti n maa se je awon isele ti won ko soju mi. Awon alaye naa je eyi to jade lati owo awon olopaa ati ohun ti awon eniyan to sun mo mi so fun mi leyin gbogbo isele naa. 


Olayemi Oniroyin mo dupe, irawo re ko ni womi. Amin.
Itan igbesi aye mi si n tesiwaju….

Ojo kinni, ojo keji won ti bere si ni wa mi kiri nigba ti won ko ri mi nile. Oko anti mi ati anti mi ti lo repootu fun awon olopaa wi pe won wa Morufa Yekeeni. 

Awon Olopaa gba oro sile lenu won. Gege bi mo se gbo gan-an, a le ojo ti won ko ti ri mi ni anti mi ti fo de odo awon olopaa. Sugbon awon olopaa so wi pe awon ko le se akosile wi pe mo ti sonu ayafi ti wakati merinlelogun ba koja. 

Ojo keji ti anti mi pada sibe ni won to wa tewo gba esun re wi pe omo sonu looto. 

Awon kan so wi pe boya mo ti tele okunrin salo ni. Awon kan ni, o le je ile okunrin kan ni Morufa lo ba si baun.
Orisirisi oro ni awon eniyan ti n so ladugbo. Awon kan ni boya anti mi o toju mi daada ni mo se poora bi iso.
Awon olopaa bere iwadii won. Won ni se mo ni oko afesona tabi se won mo okunrin kankan mo mi.
Awon ti won mo emi ati Santana papo jewo fun awon olopaa. 

Iroyin wi pe mo ti sonu ti de odo awon iya mi ni ile wa to wa ni Amuloko, Ibadan. Ojo keji ti iya mi gbo lo de s'Eko pelu egbon mi. Aburo baba mi okunrin kan naa tele won, gbogbo won si je meta papo. Iya mi ti di radarada nigba ti yoo fi de siluu Eko leyin ojo meta ti won ti n wa mi. 

Joojumo naa ni anti mi n sunkun, gbogbo ile lo n wa mi, won o si mo ibi ti won le wa mi si. 

Santana naa ti gbo wi pe awon olopaa ti n wa mi, bakan naa lo si gbo wi pe won ti daruko re gege bi afesona mi. Bo se gbo lo ti salo. Enikeni ko si mo ibi to sawo. 

Sisalo ti Santana salo mu ifura dani fun awon eniyan ati awon olopaa. Won ni o seese ki Santana mo ibi ti mo wa ati ohunkohun to le maa sele si mi lowolowo. A bi ki lo le mu salo lai se wi pe o lebo leru? 

Owo awon olopa te awon ore Santana bi meji, won jewo ibi ti Santana salo. Won ni lodo egbon re to wa ni Badagry lo wa. Awon olopa ba gba ona Badagry lo lati lo mu Santana.

Se won ri Santana mu? Oro wo ni won rigba lenu Santana? Ki lo n sele si mi nile babalawo ti mo wa? Gbogbo re pata le o gbo pata ti ko ni ku eyo kan.


Emi Ni Ti Yin Ni Tooto,
Morufa Eko
















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment