Ubong Etu Nbomang, eni odun merindinlogbon (26) ni egun eyin (opa eyin)re ti kan nibi to ti n yoju wo oga re obirin ninu baluwe.
Ilu Asaba to wa ni Ipinle Delta ni isele yii ti gbe waye. Gege bi akojopo iroyin Olayemi Oniroyin Agbaye se so, igba akoko ko ni yii ti Ubong Etu Nbomang ti maa n yoju wo oga re, eni ti ojo ori re le ni ogbon, ni akoko to ba n we lowo.
Sugbon gege bi oro Yoruba, ojo gbogbo ni tole, ojo kan bayii ni toloun.
Ore oga re kan lo wole de lojo kan, ko ba enikeni ni yara igbalejo si sugbon o n gburo wi pe enikan an da omi sara ni baluwe.
Ore oga ba rin sunmo enu baluwe, sebi ore kii se ajoji ile naa rara. Igba ti o debi ti ore re ti n we, omodo re okunrin lo ba ti n yoju wo ikebe ati oyan oga re. Bo se n yoju wo oga re bee lo gba nnkan omokunrin re mu to sin fi owo rin nnkan omokunrin re mole bi igba eniyan rin paki.
Ariwo ti ore oga pa, " Haa! O n yoju wo idi oga re e." Eleyii lo mu Nbomang ta giri lojiji. Nibi o ti fe sa ni omi ti yo o, o subu, egun eyin re si da gbau.
Oga sare jade ni baluwe pelu ose lara. O ba omoodo re nile nibi o ti nje irora to si n gbin bi eni ti won gbe obe le lorun. Bee lomoodo n wi pe, " Madamu, e darijin mi ise satani ni. E dakun, e gbe mi lo si osibitu, ara n ni mi."
O ga pe dereba wi pe ko wa gbe lo si osibitu wi pe oun bo wa ba won.
Lara oro enu oga, o ni oun sakiye wi pe won ti lu awon iho kan si ara ilekun baluwe eleyii ti ko si nibe tele. Ati wi pe gbogbo igba ti oun ba rin lo ni omoodo ohun maa teju mo isale ara oun lateyin.
Federal Medical Centre to wa ni Asaba ni Ipinle Delta naa ni won gbe lo, awon dokita si ti se ileri wi pe omokunrin naa yoo gbadun.
0 comments:
Post a Comment