Awon Yoruba bo, won ni okun ko le gun gun gun ko ma nibi to ti wa. Gege bi iwe Oba Isaac Akinyele se so fun wa, nnkan bi senturi kerindinlogun (16 century) ni won da Ìlú Ẹ̀bá-Ọ̀dàn eleyii to pada di Ibadan sile.
A mo nnkan bi odun 1829 ni a le so wi pe iran Yoruba bere si ni se alakoso ilu naa.
Baale ni oye ti won ti n je ni ilu Ibadan, bi won si se n je niyii titi di odun 1936 ti won yi pada si Olubadan nigba ti won bere si ni joba.
Oba Isaac Akinyele tun so ninu iwe re, 'Itan Ibadan' eleyii ti won gbe jade lodun 1911 wi pe apapo awon jagunjagun lati awon ile Yoruba ti won bori Fulani ni won koko te ilu Ibadan do leyin ti won le awon Fulani danu sigbo. Eleyii si wa lara ohun to mu ilu Ibadan je ilu to lagbara ju lo ni akoko naa.
E Je Ka Wo Oriki Ilu Ibadan
Ibadan mesi Ogo, nile Oluyole.
Ilu Ogunmola, olodogbo keri loju ogun.
Ilu Ibikunle alagbala jaya-jaya.
Ilu Ajayi, o gbori Efon se filafila.
Ilu Latosa, Aare-ona kakanfo.
Ibadan Omo ajoro sun.
Omo a je Igbin yoo, fi ikarahun fo ri mu. Ibadan maja-maja bii tojo kin-in-ni,
eyi too ja aladuugbo gbogbo logun,
Ibadan ki ba ni s'ore ai mu ni lo s'ogun.
Ibadan Kure!
Ibadan beere ki o too wo o, Ni bi Olè gbe n jare Olohun.
B'Ibadan ti n gbonile bee lo n gba Ajoji.
Eleyele lomi ti teru-tomo 'Layipo n mu. Asejire lomi abumu-buwe nile Ibadan.
A ki waye ka maa larun kan lara, Ija igboro larun Ibadan.
E Je Ka Wo Awon Oba To Ti Je Ni Ilu Ibadan
Ba'ale Maye Okunade (1820-1830)
Ba'ale Oluyedun
Ba'ale Lakanle
Bashorun Oluyole 1850
Ba'ale Oderinlo 1850
Ba'ale Oyeshile Olugbode 1851-1864
Ba'ale Ibikunle 1864
Bashorun Ogunmola 1865-1867
Ba'ale Akere I 1867-1870
Ba'ale Orowusi 1870-1871
Are Ona Kakanfo Obadoke Latosa 1871-1885
Ba'ale Ajayi Osungbekun 1885-1893
Ba'ale Fijabi I 1893-1895
Ba'ale Oshuntoki 1895-1897
Ba'ale Fajinmi 1897-1902
Ba'ale Mosaderin 1902-1904
Ba'ale Dada Opadare 1904-1907
Ba'ale Sunmonu Apampa 1907-1910
Ba'ale Akintayo Awanibaku Elenpe 1910-1912
Ba'ale Irefin 1912-1914
Ba'ale Shittu Latosa (son of Are Latosa) 1914-1925
Ba'ale Oyewole Foko 1925-1929
Olubadan Okunola Abass 1930-1946
Olubadan Akere I 1946
Olubadan Oyetunde I 1946
Olubadan Akintunde Bioku 1947-1948
Olubadan Fijabi II 1948-1952
Olubadan Alli Iwo 1952
Olubadan Apete 1952-1955
Oba Isaac Babalola Akinyele 1955-1964
Oba Yesufu Kobiowu July 1964 -
December 1964
Oba Salawu Akanni Aminu 1965-1971
Oba Shittu Akintola Oyetunde II 1971-1976
Oba Gbadamosi Akanbi Adebimpe 1976-1977
Oba Daniel 'Tayo Akinbiyi 1977-1982
Oba Yesufu Oloyede Asanike I 1982-1994
Oba Emmanuel Adegboyega Operinde I (1994-1999)
Oba Yunusa Ogundipe Arapasowu I (1999-2007)
Oba Samuel Odulana Odugade I (2007- titi di akoko yii)
E ma gbagbe wi pe Ifafiti akoko ni ile Nigeria lale wu jade ni ilu Ibadan lodun 1948. Ibadan naa si ni ilu to tobi ju lo ni iwo-oorun ile Afirika. Bakan naa, ko si ba se fe menu ba itan Ibadan ti a ni menu ba "Alaafin Molete", Lamidi Ariyibi Akanji Adedibu, oloselu nla to file boora lodun 2008.
0 comments:
Post a Comment