Dafiidi Adedeji omo Adeleke ti gbogbo eniyan mo si Davido ti kuro lomode ti n fi igba kekere bomi mu leti odo. Bo tile kere loju, okiki, ola ati iyi ti mu "leke" bi oruko baba to bi i lomo.
Ibi ti agbara pin si ni ilu Mali, ile funfun nla to je ibugbe Aare orileede naa, Ibrahim Boubacar Keïta, ni omo baba olowo wo lo ni Bamako ti enikeni ko si daduro lenu bode. Bi won tile fe da duro, orin "E Ma Da Mi Duro" to ko wole ko je ki won le se bee.
Aare ilu Mali yesi, o si ni okan lara irawo olorin ile adulawo ti ko se fowo ro seyin ni omokunrin ti a bi lodun 1992 siluu Atlanta, Georgia to wa ni orileede Amerika.
Bi o tile je wi pe ile ola ni won ti bi i, goolu ati fadaka ni won si fi too dagba. Sibesibe o pinnu lati tun ara re bi gege bi Wasiu Olasunkanmi Omogbolahan Ayinde Omo Anifowese baba Ajobi Farouq se so ninu orin re.
Ibi taa ti bi ni ko nii se pelu iru eniyan ti a je tabi da laye. Aimoye awon omo olowo ti won ti baye ara won je; aimoye awon omo oba ti won ti jaye ajerorun.
Bi won ba bi ni, aa tun ra eni bi ni. Ma ranti omo eni ti iwo n se nibi gbogbo ati nigba gbogbo. Ni ipinnu fun iru igbe aye to wu o gbe, si ma je ki ohunkohun ja ipinnu re gba mo o lowo.
0 comments:
Post a Comment