Laipe odun, aimoye awon eniyan ni yoo padanu ise won ti won yoo si di eni ile raurau ayafi ti won ba jafara.
Laipe odun si, aimoye awon eniyan ni yoo si di olowo-oloro jaburata laaarin igba perete lai se wi pe won jale tabi sise dudu.
Ki n to tesiwaju, gege bi Ojogbon Akinwunmi Isola se so, baba se alaye isowo awon eda eniyan kan gege bi
Sawo-Sogberi. Sowo-Sogberi je awon eniyan kan ti won ki i se ojulowo sugbon ti won se bi gidi.
Loju awon ogberi won a maa sebi awo gidi sugbon ti won ba ri awon awo won yoo di ogberi alailabula.
Mo tun fe pada sori alaye mi nipa awon ohun ti ko ni pe sele. Abi ki n pe ni asotele eleyii ti ko ni pe waye.
Awon ohun ti yoo sele ti ko ni pe ni, eleyii to si ti n foju han bayii. Ninu awon apileko mi ti mo ti ko saaju, nibi ti mo ti n so nipa ibere pepe ise iroyin sise ni ile adulawo.
Kosi ohun ti n je ise iroyin sise nibere pepe, ti ohun kan ba wa gege bi jijabo isele, eleyii le wa bi aheso, ofofo tabi oro ori irin lasan.
Eleyii ti pupo re maa n waye ni akoko ti won ba na awon oja nla laye atijo.
Awon eniyan ti won sise to jomo ise iroyin sise ni awon olorin ibile wa.
Awon eniyan ti won sise to jomo ise iroyin sise ni awon olorin ibile wa.
Awon isele to sele ni awon agbegbe kan maa jeyo ninu awon orin won gbogbo ti won ko. Sugbon igba to ya, ojulowo awon oniroyin ti won kose iroyin san-ansan jeyo, eleyii to si fi awon olorin pamo gege bi oniroyin.
Sugbon lode to ni, opolopo awon oniroyin ni won ti n padanu ise won latari wi pe awon ile ise iroyin ko ri owo osu won san fun won.
Awon ti won ri owo gba, owo ti won san ko se mu dele lati gbo bukata won. Sugbon eleyii ko so wi pe ko si owo nidi ise iroyin sise.
Fun awon ti won si lero lati maa se ise iroyin bi ti aye atijo, awon nnkan ti mo salaye saaju seese ko je iriri won. Sugbon awon oniroyin olaju yoo leke, ti awon ewu wonyii yoo si fo won ru.
Ohun to fa eleyii ko tayo olaju to ti goke agba nipase ero ayelukarabiajere. Ni aye igba kan, eni ti o kose iroyin ko le sise iroyin, ko si ile ise iroyin ti o gba iru won.
Iwomba awon eniyan ti won ko ojulowo ise iroyin sise ni won se yatayoto nidi ise opolopo to pawo wole.
Sugbon nipase ero ayelukarabiajere, aimoye awon sawo-sogberi ni won ti sawo ise iroyin sise.
Ohun to wa pa awon ojulowo oniroyin lara tun ni wi pe, ki iwe iroyin to jade, iroyin awon oniroyin sawo-sogberi ti jade sita.
Oju ese ni iroyin won, ko si tun na awon eniyan lowo pupo bi rira iwe iroyin lati ri iroyin won ka.
E yii to tun soro ju lati gbagbo ni wi pe opo awon oniroyin ayelukarabiajere eleyii ti opo won je sawosogberi ni won tun ri owo mu ju awon ojulowo oniroyin lo.
Apeere iru awon oniroyin beeni ni Linda Ikeji, owo ti omobirin naa n ri laarin ose kan, ojulowo oniroyin le ma ri laaarin odun marun-un; asodun ko rara.
Lara akiyesi mi tun ni wi pe, ise iroyin ti n fo lo awon ilu o keere.
Kini itunmo eyi? Nipa iranlowo ayelujara, oniroyin le wa ni ile alawo funfun ko maa jabo tabi ko iroyin fun ile ise iroyin to wa nile adulawo.
Iru oniroyin bee le ma ko iroyin fun awon ile ise iroyin bi marun-un si mefa kaakiri agbaye eleyii to le so awon oniroyin ti won gbe ni ileto ti ile ise iroyin bee wa di alairi ise se.
Igba kan nbo, awon ti won ti yo yoo tun maa ri opolopo ounje je nigba ti awon ti ebi n pa ko ni ri ohunkohun je rara.
Ohun ti yoo si juwe ipo ti oniroyin yoo wa niise nipa ogbon ori, imoose (bi won se mo ise to) ati ogbon atinuda.
Sugbon fun awon oniroyin ti won ba gbon, iyen awon oniroyin ti won ba jafara, o di dandan ki won ba igba yi ki won ma ba di eni ana.
Ohun ti n sele yii gan-an taba awon telifisan ati redio, laipe aimoye awon eniyan ni o ni anfaani lati gbe ohun si afefe lai se wi pe won ba ile ise redio tabi telifisan sise.
Ero ayelujara si n bo wa gberu, eleyii ti o mu lagbara lati jafafa ju eleyii ti a n lo lode oni.
Bi ero ayelujara si se n gberu si ni owo nina ati je anfaani re yoo ma diku sii.
Ohun ti o sele ni wi pe, aimoye sorosoro ni o ni anfaani lati le da ile ise redio kale lori ero ayelujara eleyii ti aimoye awon eniyan lagbaye yoo si ni anfaani lati gbo ketekete pelu owo tasere tabi lai nani ni kobo.
Opolopo awon sorosoro tabi oniroyin ti won ba lebun to joju, ogbon ori to peye, imoose ati ogbon atinuda to lekenka ni won yoo di ohun awati ni awon ile ise igbohunsafefe ni ero ati da duro ti won loto.
Nitori anfaani ati daduro yoo rorun nipase ero ayelujara. Aimoye awon ile ise iroyin ni o si kogba wole.
Ohun ti yoo wa seku fun oniroyin igbohunsafefe lati rowo mu ni ogbon atinuda, imoose, ati imo-dogbon to kun fofo.
Nnkan yi pada, kii se nidi ise iroyin nikan. Awon ise ti won ti n gba eniyan mewaa ti di ohun ti eniyan meji lese nipa iranlowo awon ero igbalode.
Eniyan melo ni se amulo apo ifiweranse lati fi leta ranse laye ode oni? Bi won tile n se bee, ko dabi ti aye atijo mo.
To baya, awon onise ilepo ko ni si nidi ero ti n ta epo mo fun awon oko to ba fe wa ra epo. Fun ara awon onibara ni yoo maa ta epo fun ara won, kaadi ni won yoo si fi maa sanwo.
Igba n yii, awon eniyan to ba jafara ni won se akiyesi eleyii. Fun awon ti won ko jafara, igba o lo mo won lara.
Ohun ti eniyan le se lati gba igba mu naa ni lati wa ogbon ati imo tuntun ko, nitori ogbon ana ti di omugo lonii.
Awon moto tuntun orisirisi ti ko si laye bi nnkan bi odun mewa si ogun odun seyin ti wo igboro, opo awon mekaliiki atokose to je wi pe orisi awon moto atijo ni won moo tunse gbodo wa ogbon da ki ounje won maa ba tan.
Orisi ise yowu ti eniyan le maa se, o ti di dandan fun eniyan lati wa ogbon ati imo tuntun to ro mo ise naa. Ti eniyan ko ba jafara, yoo di eni ile raurau laaarin odun perete sii.
Ise tisa ti ko gbayi lonii, aimoye awon eniyan ni yoo di olowo osan gangan nidi ise tisa latari wi pe won se amulo ogbon tuntun.
Igba kan n bo, ti tisa to logbon lori yoo maa ko awon omo leko kaakiri agbaye lai se wi pe o kuro ninu ile re.
Ti owo o si maa wole fun un nigbogbo gba bi eni to seso.
E maa gbagbe ohun ti mo wi, e wa ogbon ati imo tuntun to ro mo ise yin.
Eekeji, eni lati setan lati ba igba yi nipa sise amulo anfaani ti olaju mu wole.
Eeketa, ogbon atinuda yin gbodo wayami.
Olayemi Oniroyin ni oruko mi. E se fun akoko yin ti e fi sile lati aka apileko mi.
0 comments:
Post a Comment