Ogbeni Yanju Adegboyega to je igbakeji olootu magasin-inni Alariya Oodua ti se alaye bo se ba igbati pada lowo soja alaso dudu.
Ogbeni Gbenga Olokede, alaga egbe akoroyin fun eka ile ise BCOS ti Ipinle Oyo bu enu ate lu iru iwa ti olopaa naa wu si oniroyin. O si tun jeje lati se atileyin fun Ogbeni Yanju Adegboyega nipa fifi okunrin olopaa naa jofin.
"E gbani, e laja!!!
Okunrin olopaa kan lara awon to n pese aabo nibi igbejo awuyewuye to waye ninu eto idibo gomina to
koja nipinle Oyo n'Iyaganku, AJAKAIYE RAPHEAL gba mi leti laipe yii.
Loooto lawon to ku re be mi, nigba ti mo ni alukoro ileese olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adekunle Ajisebutu fe ba eni to ba je oga laarin won soro.
Sugbon, emi mi ko foriji okunrin naa.
Diafoo, mo fe ko iwe ehonu si oga agba olopaa lorileede yii nipase komisanna olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Muhammad Katsina.
Nitori mi o mo ese ti mo se, bee si ni okunrin naa ko se bi igba to mo poun se
aidaa rara bawon to ku re se n be mi.
Ki n to pari oro mi:
Eyin iya ni mo fe be na. E ma tii maa da seria fun okunrin olopaa naa bayii, e je ko se die."
Ogbeni Gbenga Olokede, alaga egbe akoroyin fun eka ile ise BCOS ti Ipinle Oyo bu enu ate lu iru iwa ti olopaa naa wu si oniroyin. O si tun jeje lati se atileyin fun Ogbeni Yanju Adegboyega nipa fifi okunrin olopaa naa jofin.
0 comments:
Post a Comment