Awon onimo eda-ede ti a mo si linguistiiki (imo nipa iseda ede) gba wi pe ohun elemi ni ede je.
Eleyii lo fa ti a fi ni awon ede atijo ati ede tuntun ninu ede Yoruba ati awon ede to ku lagbaaye. Odun 1906 ni won bi Gilbert Highet to je omo ilu Scotland, odun 1978 lo si pada ko gbogbo ogbon ati imo re sinu koto gege bi onise alakada ati onkowe to gbajumo ni asiko re.
Sugbon lara oro re to fi sile lo je okan lara eroja ti awon onimo eda-eda n se amulo re lojo toni.
"Ede je ohun abemi. Eleyii ti a wa gan-an le fura wi pe o n yi pada. Abala re kan le di arugbo: eleyii ti won yoo doku ati ohun igbagbe. Awon orisii tuntun mi-in si n je jade, won ruwe, won tan kale di igi nla, won gbale won si bere si ni tan kiri". - Gilbert Highet
Lara ohun kan ti o le mu wa gba wi pe lotito ni ede n dagba sii ni ona ti a n gba ya ede kan lati inu ede mi-in. Gege bi a se ri pupo ninu awon ede Yoruba eleyii ti a ya lati inu ede Larubawa, ede Geesi ati ede Hausa.
Ona keji ni sise atunse si awon ede ti a ti n lo tele. Yato si eleyii, iseda ede tuntun tun maa n waye ninu ede. Eleyii to n se idasile ede tuntun ti awon eniyan ko mo tabi gbo tele ri.
Awon ede ti ko ba ni iru awon iyipada ti a menu ba loke yii, a le gba wi pe iru awon ede bee ko ni pe parun nitori wi pe idagbasoke ko de ba won.
Odun 2013, Tiwatope Savege aya Balogun ti gbogbo eniyan mo si Tiwa Savage mi igboro titi pelu orin re kan to pe ni "Eminado". Yato si wi pe orin naa bode pade eleyii ti tomode tagba tewo gba, akole orin naa ko awon eniyan lominu nitori ede ajoji ni.
Olootu orin naa, to tun je agbeteru fun Tiwa Sgavage, Don Jazzy, se alaye wi pe oun ni oun seda ede tuntun naa. Itunmo re naa si ni "oriire". O ti le so wi pe aimoye awon eniyan ni won ti n so awon omo won ni Eminado.
Gege bi oro Alagba Adebayo Faleti, eleyii to se ninu ewi re kan to pe akole re ni Onibode Lalupon.
O ni, "Ko seni to m'ede ayan bi eni o mu kongo ilu dani. Eni gbe omele dani lo mo ohun ti olomele n so."
Niwon igba ti o ti je wi pe Don Jazzy to se idasile ede tuntun naa so ohun ti Eminado tunmo si, ohunkohun to ba pe e naa ti di dandan ko di itewogba ayafi ti awon onise alakada nipa imo eda-ede ba tako itunmo to fun orisii ede tuntun naa.
Ninu agbekale imo eda-ede tabi imo linguistiiki, ofin to de e ati abuda to ro mo o, aye wa fun iseda ede tuntun niwon igba ti iru ede bee ba di itewogba lowo awon alase.
Sugbon eyi ko fe e ri bakan naa pelu asa, paapa julo asa Yoruba. Asa ati ise awon eniyan je ohun idamo eleyii ti a fi n da awon eniyan kan mo yato si awon mi-in lawujo agbaye. Asa n se apejuwe iru eniyan taa je, igbagbo wa, iran wa tabi ibi ta a ti se wa.
Titewo gba asa alasa le mu wa padanu igbagbo wa ati iru eniyan kan pato ti a je.
Lara asa tuntun eleyii to ti bee si ni gbile bayii laaarin awon eniyan alawo dudu, ati awon Yoruba, ni sise Ajoyo Omo Tuntun Ninu Oyun.
Eleyii maa n waye nigba ti obirin ba si wa ninu oyun ti ko ti bimo.
Iru obirin bee yoo pe awon ore re jo lati ba yo. Awon ore naa yoo wa pelu orisirisi ebun, ayeye weje-wemu yoo si waye nibe.
Iya omo naa yoo kede fun awon ore re boya obirin ni omo ti n bo waye tabi okunrin ni. Won o ge akara oyinbo, won si ya opolopo foto lati fi se iranti ojo naa. Orisi asa yii kii se asa ile Yoruba, o tako igbagbo ati ise awon eniyan dudu pelu.
Ayeye ajoyo omo tuntun nigba to wa ninu oyun yii la le so wi pe o bere ni nnkan bi Senturi mokanlelogun seyin ni ile Giriki ati Ijibiiti.
Ohun ti won se nigba naa kii se ayeye, ohun ti won se dabi igba ti eniyan ba n se etutu tabi irubo nitori eje orun to wa ninu oyun ko maa ba nisoro laye. Eleyii ti a le ka si wi pe eniyan n se adura fun omo to n bo wa si ile aye.
Sugbon nigba to ya, awon eniyan agbaye bere si yipade ti won si n tewo gba gege bi ayeye weje-wemu eleyii ti won pe ore ati ojulumo lati wa ba won yo.
Orisirisi oruko ni won si n fun orisi ayeye yii kaakiri agbaye.
Ni awon ilu ti won ti n so Geesi, "baby shower" ni won pe orisi ayeye yii. Ayeye yii kan naa ni won mo si 'Sat' ni ilu Bangladesh. "Cha de bebe" ni ilu Brazil, nigba ti won pe ni "Manyue" ni ilu China.
Orisi ayeye yii ti de ilu Nigeria bayii, eleyii ti pupo awon amuludun; awon olorin ati awon onise tiata ti bere si ni fi lole fun wa gege bi ara asa ile wa.
Sugbon nipa sise ayewo igbagbo ati ise Yoruba, gbogbo wa la o gba wi pe eleyii kii se asa Yoruba rara.
O dabi igba ti eniyan ti bere si ni ka iye oromadie nigba ti adiye agbebo ko ti pa eyin re. Yoruba kii se bee. Yoruba gba wi pe aimoye alangba lo dakun dele, a o mo eyi tinu-un run.
Iru ajoyo bee dabi igbi ti eniyan n gbe ara re laye lowo ni, nigba ti o fi oyun inu sinu ewu nla. Yoruba gba wi pe aimoye awon eniyan ni won feje pupa sinu ti won tuto funfun jade.
Oju lasan la ri, ore o denu; inu eda jin pupo. Awon igbagbo Yoruba ni yii, eleyii to mu wa gba wi pe lotito iru asa bayii ko le ba igbe aye wa dogba.
Ibi ni maa ti duro, inu mi yoo dun lati ri esi yin gba nipa ero yin pelu asa tuntun to gbode.
Olayemi Olatilewa
@OlayemiOniroyin
0 comments:
Post a Comment