Helen Mukoro |
Ko to di wi pe ma kan lu agbami oselu ti n gbona felifeli bayii ni ilu Spain, nibi ti Arabirin Helen Mukoro to je omo ipinle Delta lati orileede Naijeria ti setan lati dije fun ipo aare orileede Spain, mo royin ki e gba mi laaye ki n ti owo bo itan awon isele to sele bi nnkan bi ogota si aadorin odun seyin ni ilu Amerika.
Sebi won ni bi omode o batan, yoo ba aroba. Awon agbalagba ile Yoruba ni won ni aroba ni baba itan.
Kini je itan? Kini je aroba?
Ti e ba fun mi laaye die si, mo fi dayin loju wi pe mejeeji ni maa salaye lai senuku sibi kankan.
Odun 1929 ni won bi gege bi alawo dudu omo ile Amerika ni Atlanta, Georgia to wa ni orileede Amerika.
Jije alawo dudu omo ile Amerika tunmo si wi pe orirun re tabi iran re se wa lati ile Afirika to je ile adulawo.
Nnkan bi ago mefa koja iseju kan, lojo kerin osu kerin, odun 1968 ni awon agbanipa yin-in ni bajinatu lojiji ni ile itura Lorraine to wa Memohis, Tennessee latari wi pe enu re ti mu ju nipa jija fun eto omoniyan, paapa julo, eto awon omo adulawo ile Amerika ati iponlogo re eleyii to lodi si eleyameya ni ilu Amerika.
Bi won tile seku pa a ninu agbara eje to n san bi omi odo Ogunpa, sugbon ero re ati igbagbo re ko ba a wonu ese mefa lo.
Ni awon akoko yii, ilu Amerika je ilu ti won ri awon alawo dudu omo ile Amerika gege bi awon eniyan ti ko dogba pelu awon alawo funfun omo ile Amerika.
Won on te eto awon alawo dudu mole, won si n re won je nigbogbo ona.
Itan tile so fun wa wi pe won ko ka awon alawo dudu si eniyan eleran-ara, oju eranko inu igbo ni won fi n wo awon eniyan ti awo won ba dudu.
Bi alawo funfun ba wo inu oko nla akero, to ba ri alawo dudu lori ijokoo, ofin ilu Amerika nigba naa so wi pe ki eniyan dudu dide naro fun alawo funfun lati joko.
Iru igbe aye yii je ohun ti akoni yii lodi si nigbogbo ojo aye re gege bi alawo dudu omo ile Amerika.
Ni odun 1965, o salaye fun awon oniroyin wi pe ile Amerika je awon eniyan dudu ni gbese pupo gan-an latari imunisin tabi imunileru awon eniyan dudu to ti waye ni awon igba kan seyin ninu itan ile Amerika.
O ni nipa sise eleyii, ile Amerika ti jebi tite eto omoniyan loju mole. Lara awon esun mi-in to menu ba ni ifiyajeni lona aito.
O ni nipa sise eleyii, ile Amerika ti jebi tite eto omoniyan loju mole. Lara awon esun mi-in to menu ba ni ifiyajeni lona aito.
Lori awon esun mejeeji yii, o beere fun aadota bilionu owo ile Amerika ($50B) gege bi owo itanran lati san fun awon eniyan alawo dudu omo ile Amerika ati awon alaise ti won ti te eto won loju mole.
Martin Luther King Jr ko si mo lonii, won seku pa baba Yolanda Denise King leni odun mokandinlogoji (39).
Won pa oninuure nibi o ti gbe n sise Oluwa oba, awon ika eniyan pa oko Coretta Scott King nibi o ti gbe n kilo iwa ibaje.
Sugbon oro akoni to so kale lodun 1963 ni awon onkotan agbaye so wi pe yoo maa wa titi lae bi Opa Oranmiyan ti n be lode Oyo Oba Lamidi Adeyemi III.
"Mo so fun yin, eyin ore mi. Bi o tile je wi pe a n dojuko isoro toni ati tola, mo si lala. O je ala eleyii to ridi mule ninu ala ile Amerika. Mo lala wi pe ojo kan orileede yii yoo dide lati gbe igbe aye to ni itunmo otito gege bi igbagbo re: ' A di otito yii mu gege bi eri ti wa, wi pe aparo kan ko ga jukan lo; ibi o si ju ibi lo.'Mo ni ala wi pe lojo kan, ni ori awon oke pupa to wa ni Georgia, awon omo eru igba kan ati awon omo olowo eru igba kan won yoo le joko papo lori tabili kan naa gege bi tegbon taburo."
Die lara oro Martin Luther King niyii eleyii to se niwaju opo eniyan ni ojo kejidinlogbon osu kejo odun 1963 ni Lincoln Memorial, Washington D.C.
Ni akoko ti Martin Luther King n ro ala re fun awon eniyan nipa ojo iwaju awon eniyan dudu ile Amerika lodun 1963 ni ilu Washington, Barack Obama, omo ile Amerika alawo dudu, eni ti iran re se wa lati orileede Kenya, wa ni Honolulu leni odun meji nibi to ti n yi taya kiri adugbo ni orileede Amerika kan naa.
Leyin odun merindinlaadota (46) ti Martin Luther King ti ro ala re fun gbogbo aye, Barack Obama wo inu ile nla funfun lo ni Washington D.C. gege bi aare ile Amerika akoko ti o je alawo dudu.
Ala Martin Luther King wa si imuse nigba ti ilu Amerika gbe Barack Obama soke lodun 2009.
Nje a tun le fi okan si i wi pe ala yii kan naa maa wa si imuse ni ilu Spain?
Arabirin Helen Mukoro to je omo ipinle Delta lati orieede Naijeria wo ilu Spain ni odun 1992 nibi ti omobirn naa ti rese wale to si ti ridi joko remuremu.
Onkowe ni, amofin ati agbaoje nipa ise otelemuye to dangajia tun ni pelu. Ninu osu karun-un odun yii, omobirin naa gbe apati lati du ipo alase ilu Denia to wa ni orileede Spain sugbon to fidiremi.
Isubu yii ko da omi tutu si lokan rara pelu bo tun se dide lati gbe apoti ibo fun ipo aare orileede naa.
Helen Mukoro ti da egbe oselu sile eleyii to pe ni Union De Todos, labe egbe oselu yii naa ni yoo si ti maa dije fun ipo aare eleyii ti yoo waye ninu osu kejila odun taa wayii.
Gege bi alaye Helen Mukoro, itunmo Union De Todos to je oruko egbe re ni "wiwa ni isokan."
Ibeere ti n fi maa kadi alaye mi naa ni wi pe: n je awon eniyan ilu Spain le fi owo sowopo pelu isokan lati gbe alawo dudu akoko wole gege bi aare orileede naa?
Olayemi Olatilewa ni oruko mi, ala mi ati igbagbo mi ni wi pe ni ojo kan, eni ti n je eran ogunfe , uyan Ekiti ati obe egusi ko ni loun jaye mo, nitori teru-tomo ile yii ni o maa fi ayokele se faaji lo je eja tutu nirole.
Olayemi Olatilewa
@OlayemiOniroyin
0 comments:
Post a Comment