Smiley face

Ogun Omode Ko Le Sere Fun Ogun

O je ohun to ba ni lokan je, eyi si wa lara iriri to seese ki n maa gbagbe laelae. Akiyesi igbe aye fi ye mi wi pe aimoye imo iyebiye ni eda le ba pade lai se wi pe enikan peni joko salaye ohun to ruju bi igba omo ile iwe joko kawe ni kilaasi.


Mo ranti Musa lonii, okan lara awon ore mi ni Musa je nigba ti mo wa ni ile eko alakobere. Ile Eko Alakobere Metodiisi ti o wa ni Ekotedo ni mo lo ni ilu Ibadan. 

Akoko eko mi yii si je okan lara igbe aye mi to dun pupo. Orisii igbe aye ti o je wi pe ere sise loba awure. Igbe aye ti o je wi pe ko si ohun meji ju ayo lo, a ko le ohunkohun bakan naa ni nnkankan o si le wa.
Mo feran Musa, ki se wi pe nipa wi pe emi re je ore timotimo bikose akiyesi mi nipa re nitori wi pe o je olopolo pipe eniyan. Eyi si maa n je ki n wo gege bi akanda eniyan kan.

Musa le ma wa si ile iwe fun odindi ose meji, igbakuugba to ba wu ko yoju, ko si ibi to wu ka ti de lori ise kan ti ati n baabo, kosi bi ise ohun sele le to loju wa, Musa o tun tayo ju gbogbo wa lo ni koda ko je asiko idanwo nikan lo yoju.

Orisii opolo Musa a maa ba mi leru nitori mi o fi ibi kankan sunmo nibi ise opolo bio tile je pe joojumo lemi n wa si ile iwe. A si maa wu mi ki n dabi Musa omo Ibrahim.
Musa nikan ko lowu mi ki n jo. Okan lara awon ore mi kan naa tun wa to tun fara pe e, Hamzat. Kii se opolo pipe lo mu Hamzat wu mi. Sugbon mo feran Hanzat nipa ewa ara to ni.

Ti won ba ni okunrin rewa, ati ojo ti won ti bimi saye mi o ti ri iru ewa Hamzat ri. Hamzat mo fefe, pupa re si la kedere bi oye la kari aye. Irun ori re a maa gbon leuleu bi o ba n rin lo bi irun eebo. (Omo Niger Republic loke oya loun ni iya re, won si ni iya re lo fi irun naa jo).

Hamzat tun ni orisii ohun(voice) kan eyi ti o je wi pe ti o ba n binu soro eniyan o le mo wi pe oun binu ni. Ki ohun eni o tutu ko si maa si agbara ibinu to le yi pada kuro ni ipo re.

Lonii ile to mo, opolo Musa o wu lo mo, ewa ara Hamzat ti baje. Ko wu mi ki n dabi okankan ninu awon ore mi ti mo salaye soke yii mo nitori orisii igba aye ti won yan ti dori ohun gbogbo kodo latari isesi, iha ati iwa won si igbe aye.

Imo je ohun to se koko si igbasi aye eda. Ebun nini si tun je ore-ofe lati odo Olorun lati se aponle eda fun igbega. Sugbon olubori ibe ni iwa. Awon kan pe ni isesi tabi iha. Ohun kan naa ni gbogbo re ja si.
Isesi eni lo maa n fi iwa owo eni han. Iwa owo eni si ni opakutele si iha eni si ohunkohun ti a ba gbe dani tabi doju ko laye.

Bi Musa se ni opolopo opolo to fun iwe kika, iha to ko si eko re pada so imo re di akurete. Ohun ti oluko ko wa laaarin wakati kan seyin, agaga ti a ba jade lo sere ki a to tun pada si kilaasi, maa ti gbagbe opolopo nnkan ti won ko wa. Bi Musa ba sa ni ile iwe fun ose meji, eyo woro kan eko to ti ko seyin ko ni bo sonu lopolo re.

Igba meji otooto ni mo tun yara ikawe meji otooto ka nigba naa. Musa o tun yara kan ka leemeji ri.

Emi pada wo ile iwe girama, Musa o le lo. Won tun gbami wole si Ifafiti, Musa gbiyanju sugbon aso o ba Omoye mo. 

O ku die ka jade ile iwe alakobere ni Hamzat bere si ni tele awon orekore ti won n jijo lo maa mu imukumu. Igba ti mo wo ile iwe girama, Hamzat o le wole pelu wa nitori wi pe igbo ti yi lori. O si ti bere si ni wi kantakantan kiri. Okan mi baje.

Awon obi re mu lo seyin odi lati lo toju re. Igba ti Hamzat yoo fi pada wa sile. Awo re ti si, oju re ti hun jo bi oju agbalagba, omo pupa ti jona bi eyin ape akara, irun ori re ti reje tan bi igba ogun jalu, bakan naa ni gan-angangan ko kuro lara re tan patapata.

Igba miiran yoo tutu bi omi inu amu. Bee ba n baa soro ko ni wi ohunkohun. Igba mi si ree, erin odi ni o maa rin lenu. Hamzat ko riran ri ara re debi wi pe yoo se itoju ara re gege bi o ti ye.

Musa ati Hamzat je ore mi igba kekere ti a jo lo ile iwe kan naa ti a si tun jo gbe ni adugbo kan naa. Bi o tile je wi pe ogun omode o le sere fun ogun odun. Sibesibe, sebi ojo taa ba ri ara eni o ye a dun nu ni? Hamzat o da mi mo moo lojo ti mo duro ki i, ti Musa ba ri mi a foju pamo.

Mo padanu won ki i se nipa iku bi ko se nipa igbe aye won to loju nipa iwa ati isesi won.

Kosi iru ogbon ti eda le wu ko ni laye, kosi iru ebun ti Edua oke le fi jinki eniyan, ko de si iru imo to le wa latari eni, bi eniyan ba padanu iwa tabi ti isesi eni ba kudie kaato tabi ti iha eni ba mehe, omoluabi iru eni bee ko le duro.
Orisii awon eniyan ti won ba pagede ninu iwa, abi isesi tabi iha ni Yoruba n pe ni omoluabi, eyi si je olubori fun ewa, ogbon ori ati ebun.
Musa ati Hamzat je awon ore mi ti mi o le gbagbe lailai. Musa padanu opolo pipe, Hamzat si so aye re nu lati mojesin.

Olayemi Oniroyin, gbogbo igba lokan mi maa n baje ti mo ba ranti awon ore mi meji yii.
Awon ore mi meji ti mi o le gbagbe laelae.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment