A bi eyin ko ti gbo, wi pe awon eniyan ti n fesun kan mi wi pe egbe PDP ti fun mi ni kaadi omo egbe won lati le maa tako ijoba APC to wa lode?
Ibeere isale yii la fi sita lori Facebook Yoruba Dun lati mo ero awon eniyan nipa isejoba Aare Muhammadu Buhari eleyii to da lori awon ileri ti aare ati igbakeji re se saaju eto idibo to waye ninu odun yii:
"Igba wo ni Aare Buhari fe mu ileri re se? Se kii se wi pe n se ni egbe APC gbe wa mora nigba eto ipolongo idibo? Se e si nigbagbo ninu Buhari abi e ti pa okan yin po sodo Olorun Oba nikan.
E ba wa dasi oro yii".
Lati ka esi awon eniyan nipa ero won, e le kaa labe linki isale yii:
Ohun to jomiloju ju ni bi awon kan se n soko oro ranse si Olayemi Oniroyin ati awon iko akoroyin re wi pe oloselu ni wa; ati wi pe egbe PDP la n se.
Ero wa si ni lati bi isejoba Buhari lule. Boya eleyii le je ero ti yin naa. Maa ro yin ki e ka apileko ti mo ko saaju eto idibo to waye ninu linki isale yii.
Bi o tile je wi pe mo tako iyansipo aare ile yii nigba kan ri, Goodluck Jonathan, fun igba keji. Kii se wi pe GEJ gan-an ni ko dara gege bi adari, sugbon awon eniyan to ko sodi lo ba isejoba re je.
Ibi ti Goodluck ti wa se ohun to dun mi ju lo ni iha to ko si awon asebaje inu isejoba re. Loju temi, bi igba ti n fowo ra won lori lo jo loju mi.
Bakan naa, nipa ti Buhari, bi o tile je wi pe aimoye apileko ni mo ko lati fi se atileyin fun un latari wi pe mo gbagbo ninu re. [E le ka okan ninu awon apileko ti mo ko nipa re, saaju eto idibo ninu linki isale yii:
www.olayemioniroyin.com/2015/02/idi-pataki-ti-mo-fi-fe-dibo-fun-odaju.html?m=1]
www.olayemioniroyin.com/2015/02/idi-pataki-ti-mo-fi-fe-dibo-fun-odaju.html?m=1]
E yii ko tun mo si wi pe ti Buhari ba se ohun to kudie kaato ki n moju kuro lalai kede re faye tabi fenu abuku kan-an. Sebi won ni ijoba demokresi faaye gba "o-fe-lohun?"
E mi kii se oloselu, bi iroyin ba se lo lemi se n tele e. Mi o si bikita ohun ti enikeni le so tabi se nipa sise afihan ero mi.
Ohun kan pataki tun ni wi pe, gege bi e se leto lati rogba yi enikeni to ba wu yin ka ni emi naa ni eto labe ofin.
Sugbon o di dandan fun mi lati se eleyii lori ododo; kii se nipa ki n maa pe dudu ni pupo nitori asodun.
Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Ise iroyin sise lo so mi di Olayemi Oniroyin Agbaye. Boya ni eyin mo wi pe Adewale Dada The-good, eni ti e mo gege bi sorosoro ti di oloselu nla ni Ipinle Ogun. Mo si gbo wi pe Ile igbimo asofin agba niluu Abuja n reti re laipe.
E le ka nipa okan lara awon iroyin wa to ti jade nipa Adewale Dada Thegood Alao ninu linki isale yii:
Ki n to maa lo, gbolohun yii ni maa fi kadi gbogbo re nile: E je ka gbiyanju ka sotito. Nitori otito ni o pada leke aye. Otito le koro, sugbon o daju wi pe adun ni i gbeyin ewuro.
E ku ikale!
0 comments:
Post a Comment