Smiley face

Won Ti Kilo Fun Olayemi Oniroyin Lori Oro Funke Akindele ati Toyin Aimakhu

Laipe yii ni mo se afihan aso oge Funke Akindele eleyii to fi sara niluu London nibi to ti lo se ayeye ojo ibi re to ko ninu osu to koja yii. 

E le ka iroyin naa nibi ti e ko ba tii ka tele:
www.olayemioniroyin.com/2015/08/aso-oge-funke-akindele-ta-lenu-yeriyeri.html?m=1
Leyin ti iroyin yii jade lori olayemioniroyin.com, ikanni Yoruba Dun ti won n gbe wa laruge tun iroyin naa te saye lori Facebook.

E le ye atunte iroyin naa wo lori Yoruba Dun nibi:

Iroyin yii ni Alaaja Fatimah Abdulkareem ri, eleyii ti won si koro oju si. Boya eyin ko ti le mo Alaaja Fatimah Abdulkareem. Alaaja Fatimah Abdulkareem je okan pataki laaarin egbe awon akoroyin ile Naijeria ati ni ile Afirika. 

Laarin egbe awon obirin ti won sise iroyin nile adulawo pata, odu ni Fatimah Abdulkareem, egan ni hee.
Aimoye odun ni arabirin Fatimo fi sise ni ile ise igbohun safefe BCOS to wa niluu Ibadan nile Oluyole ko to di eni apesin laaarin obirin egbe akoroyin ile alawo dudu pata.
Ohun ti Arabirin Fatimah wi ni yii:




"Ti a ba so pe Yoruba dun, e je ka tun ma hu iwa pe Yoruba dun naa ni.

Ki ni ka ti pe aso ti Funke wo yi loju ewe Yoruba dun? Omo Yoruba atata ni emi, mo si mo pe asa Yoruba ko fi aye gba ki a wo aso to fi igba aya obirin sesin bi eleyi.
Ko di igba ti a ba rin ihoho ki a to wuyi loju. Emi fe gba Yoruba dun ni imoran lati maa fi asa ati ise ti yo gbe Yoruba soke ni gbogbo ona si okan ni igba gbogbo.
Aso ti Funke wo yi ko buyi kun Yoruba ni onakona. Mo wi temi na."
Bakan naa, lori iroyin Toyin Aimakhu ati oko re Adeniyi Johnson eleyii tija ranpe sele laaarin won sugbon ti won ti pari re bayii.

E le ka iroyin naa nibi:
Nibayii ti ija ti pari, Awon ololufe Toyin Aimakhu ti bere si ni di ebi isele naa ru awon oniroyin, paapa ju lo Olayemi Oniroyin.

[E joo o! Kilo kan temi nibe? Se emi ni mo ni ki oko Toyin lo ma yan ale ni? A bi won gbo wi pe emi ni mo lo sofofo fun Toyin?]

Gege bi alaye won, won ni ahon atenu ko le gbepo lai ma sija. Ko de sibi ti ise ko si.
Sugbon ki oro ma ti toro ki awon oniroyin ti bere si ni fon kiri ori ayelukara tun bo n ba igbeyawo awon osere onitiata je sii ni. Nitori gbogbo ohun ti won ko ran won ni won yoo maa so kiri, titi ti oro naa yoo fi fe loju koja atunse.




Wayio, won ti ro Olayemi Oniroyin lati sora gidigidi ti o ba fe ri oju pipon awon ololufe Toyin Aimakhu.

Nitori kii se gbogbo ohun toju ba ri lenu n so.

















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment