Ati kekere ni musulumi ti
n ko omo re laso
E je ki n so itan kekere kan fun yin. Pasito kan an gbiyanju
lojo Satide kan lati sise lori koko iwaasu ti o lo lojo isimi. Sugbon omo
kekere kan mbe ni yara to kangun sibi ti pasito yii wa, eleyii ti erepa re n pa
ariwo si pasito leti. Pasito wa ronu iru ise to le gbe fun omo naa, eleyii ti o
fun pasito ni anfaani lati roju-raye sohun ti n se.
O boju wo ori tabili kan legbe re, o ri maapu agbaye kan
eleyii ti won ya si ori iwe nla kan feregede. Maapu agbaye naa kun fun orisiirisii
ila eleyii to wonu ara won to si jora won. Pasito ya iwe yii si welewele, o ko
fun omo naa wi pe ko lo to awon iwe to
ya naa po.
Afojusun pasito ni wi pe yoo gba omo naa ni opolopo akoko
lati rojutu tito iwe naa papo, iyen to ba pada ri to leyioreyin. Nipa bayii, pasito
yo reti gboran.
Sugbon si iyalenu pasito, omo naa pari ise naa laaarin iseju
marun-un. Pasito beere bawo ni omo naa se ri i topo kiakika bee.
“Mo sakiyesi wi pe aworan okunrin akoni kan mbe leyin maapu naa. Ninu ero mi, mo mo wi pe ti mo ba le ri aworan akoni naa topo, a je wi pe mo ti ri maapu naa to po ti mo ba yi pada seyin”.
Ogbon omode yii wu pasito lori, o si mu ogbon lo gege bi koko
iwaasu lojo isimi. Opolopo awon eniyan ni won wa igbe aye to dara lati sajo tabi
topo fun ra won. Sugbon ohun to dara ju ni lati se awari akoni inu wa. Ti won
ba se eleyii, ati ri igbe aye won gbamu ko ni nira gege bi omo naa se ri maapu agbaye
naa topo leyinoreyin.
Ojuse awon obi ni lati to omo won sona nipa iru igbe aye to
ye ki won o gbe leyinwa ola. Mi o so wi pe irugbe aye ti obi FE, sugbon iru
igbe aye to YE ki awon omo won o gbe. Awon obi le se eleyii nipa sise akiyesi
isesi, iwa ati ebun kan pato ti awon omo won ni lati pinisin. Ojuse obi si ni
lati ran omo won lowo nipa sise agbateru fun agbara tabi ebun ti omo won se
afihan re lati kekere.
Sise akiyesi ati iranlowo fun awon omo wa lati kekere yoo ran
won lowo lati mo iru ona to ye ki won o to, iru eko to ye ki won ko ati iru
awon eniyan to ye ki won gbara le lati je eniyan pataki lawujo.
Mo ti so seyin wi pe ka lo si ile iwe, ka gboye nikan ko to
mo lati bori isoro airise to wa lawujo wa. Ati wi pe kii se nipa kiko “eko to
dara ju” ni ile iwe giga lo le mu wa di eni giga. Bi ko se ironilagbara ogbon,
agbara tabi ebun amutorunwa wa, eleyii ti imo iwe se pataki pupo nibe.
0 comments:
Post a Comment