Ile ejo ti
ran Jimoh lewon leyin to fi ehin ja ori oyan asewo niluu Ibadan
Ile ejo Majisireeti ti n jokoo niluu Ibadan ti ran Ogbeni
Sunday Jimoh lewon bayii leyin igba to fi ehin ja ori oyan arabirin Meseheno Asukwo
niluu Ibadan. Ni nnkan bi ago mejo ale Ojoru to ko ja yii (21/10/15) ni Sunday,
eni odun mokandinlogun (19) lo je igbadun ara re ni ile asewo kan to wa ni
agbegbe Ekotedo niluu Ibadan. Gege bi
iwadii Iroyin Owuro, igba ti Sunday je dodo omoge tan, ko di wi pe ko sanwo asewo
lo ba bere si ni so sitoori repete fun Meseheno.
Meseheno omo yibo ba fabinu yo. Bee lo n pariwo pelu adamodi geesi
ati ede yibo wi pe ki Sunday o sanwo oja to ra ni kiakia. Meseheno ti inagije re n je Angel ba gbinyanju
lati towo bo inu apo Sunday nigba to ko ti o dalohun boro. Ibi ija ti gbe bere
ni yii, ti Sunday n fi gbogbo ara ja bi eni jagun Kiriji.
Nibi ija yii lo ti fehin ja ori oyan Angel omo pupa roboto,
to si tun fehin kola gomba si gbogbo oju re pata.
Awon eniyan sare gbe Angel lo si ile iwosan nigba ti won dana
iya fun Sunday ko to di wi pe won fa a le awon olopaa lowo. Enikeni ko le so
fun wa nipa ibi ti Sunday n gbe abi iru ise ti n se gan-an. Sugbon iwadii fi ye
wa pe igba akoko ko ni yii ti omokunrin naa ti maa wa naja awon asewo.
Lojo keji ti isele yii waye, adajo agba Majisireeti, Arabirin
Munirat Giwa-Babalola ti n jokoo nile ejo Majisireeti Iyaganku niluu Ibadan ti
dajo ewon osu mefa (6) fun Sunday nigba ti ile ejo fidi re mule wi pe bobo naa
jebi awon esun ti won fi kan an.
0 comments:
Post a Comment