Won je David Mark, Amaechi ati Fasola lenu bi obi abata
*Didake David Mark n ko awon eniyan lominu
*Asa tuntun ti won da:
“Mi o gba riba ri laye mi” - Amaechi
“Gege bi gomina, mi o saini seeki ri ”- Fasola
Awon omo
Naijiria ti bere si ni kominu pelu didake ti aare ile igbimo asofin agba ana,
David Mark, se ko ti o soro tabi dasi awon oro to n lo nile igbimo asofin gege
bi omo ile. Paapa julo, didake re ni akoko ti awon ile igbimo asofin agba n se
iforowanilenuwo fun awon minisita ti Aare Buhari fi oruko won ranse.
Gege bi omo
ile igbimo to ni iriri julo, opolopo awon omo Naijiria ni won reti idasi re
ninu awon oro to se koko sugbon ti maanu naa ko ti o soro lati igba ti won ti
gbe ile igbimo eleekejo to wa lode yii ro.
Igba
marun-un otooto ni won ti dibo yan David Mark, eni odun metadinlaadorin (67),
sile igbimo asofin agba Abuja. Ninu eto idibo odun 1999, 2003, 2007, 2011 ati
ti 2015 to waye laipe yii, David Mark naa ni igba funfun re n leke omi lati
soju Guusu Benue nile igbimo asofin ti won ti n fi aga alaso pupa jokoo.
Yato si wi
pe o ni anfaani lati jawe olubori nipa jije omo ile igbimo lodun 2011, Mark to
ti fi igba kan je alakoso ipinle Niger lodun 1984 si 1986 ninu isejoba ologun,
tun pada jawe olubori gege bi aare ile
igbimo asofin agba eleyii to jokoo laaarin 2011 si 2015. Akoko yii si fe e je
igba ti okiki re kan julo ninu oselu ile Naijiria.
Opolopo
awon eniyan ni won ti lero wi pe baba naa o lo sinmi nile nigba to ba pari ise
re gege bi aare ile igbimo asofin agba. Sugbon ninu eto idibo odun 2015, odoodun
ni sapo n ruwe ni David Mark fi oro naa se pelu bo se pada wa gege bi omo ile
igbimo asofin fun igba karun-un.
David Mark
ko di ipo agbara kankan mu nile igbimo asofin eleekejo iru e to wa lode yii,
bakan naa ni iriri re gege bi asofin to pe ju lo nile igbimo farasin ni awon akoko
tile ba pade.
Awon onwoye
lagbo oselu ati awon onimo nipa irori eda eniyan gba wi pe didake ogbeni Mark
le je latari bi pupo awon omo leyin re nigba kan se di ipo asaaju mu nile igbimo oteyii, nigba ti oun bi enikan
to n ti je oga wa pada di omo leyin to kan an jokoo lori aga lasan lai ni irawo
kankan lapa.
Lara afikun
awon onwoye tun ni wi pe, o le je boya o n gbiyanju lati fi ara re si ipo owo
(aponle) nipa didake ti n dake roro bi omi inu amu. Se e mo wi pe awon ijiroro lori awon abadofin
ile igbimo kii waye laisi ariwo pipa mora eni, riranju mora eni, eleyii to tun
maa la gidigbo lo Iawon igba mi-in. O le je awon ohun to n sa fun ni yii to fi
n sebi abata takete bi eni wi pe ko bodo tan-an tabi ko je wi pe ojuti ni o je
o soro.
O jo bi eni
wi pe awon ara ilu gan-an ko tile kobiara si bi ogbeni David Mark ko se ki n
dasi awon oro to n lo nile igbimo asofin. Sugbon ohun to pe akiyesi awon eniyan
ko ju bi kamera ile ise telifisan kan se gbe aworan Mark jade nibi to pelengo
si legbe kan , to si n wo bi eni wi pe ohun ti n lo ko kan-an rara. Eleyii waye
nigba ti ile n da ibeere orisiirisii bo Rotimi Amaechi, okan lara awon minisita
ti won fi oruko won ranse.
E jeri awon
omo Naija, kete ti won foju ri Mark ni iye won so. Ti won si se bee fo fere sori
ero iwiregbe Twitter nibi won ti n tu gbogbo oun to ha won lona ofun da sile.
Die ni yii lara awon oro to n lo lori ayelujara nipa asofin David Mark.
Musbau Bolaji: [@Bonjila] Onworan le mi kaa si.
Ohun to si maa n sele seeyan niyi nigba o ba ti pe lori imi.
Aisha: [@aisha_modibbo] Maanu naa le maa
dake latari wi pe oju n ti, ko si mo bo se fe pe Bukola Saraki ni “Mr Senate
President sir”.
AS Aruwa [@Musadiqz] David Mark, agbalagba
ana, wa di eni ti n wo bi omode ti won gba pofupoofu re lonii. Sio.
Abu Hashim [@zvyyd] E dakun sir, oga Bukola
Saraki, bi o tile je adura ibere ati ipari, e je ki David Mark naa ma se.
IG:Osi.lama: [Osi_lama] Emi ko tile kofiri baba
naa rara. Se e suo wi pe David Mark mbe nile igbimo sa?
Alade: [@alade80] Ti omo ile iwe ba ti ripiiti
kilaasi, ki lo tu ku ju ko ma wo bi ori eran lo.
Raji Fasola |
Yato si oro David Mark ti n ja raninranin lori ero iwiregbe
Twitter, awon omo Naija tun ti bere si ni dasa tuntun eleyii to jeyo latari
awon idahun Raji Fasola ati Rotimi Amaechi ti won je gomina tele fun ipinle Eko
ati Rivers leseese.
Rotimi Amaechi |
Ni akoko ti ile igbimo asofin agba n fi oro wa Fasola lenu wo,
won beere nipa milionu mejidinlogorin (N78M) to na sori ikanni adani re lori
ayelujara, www.fashola.com. Fasola ni ko si owo ti oun na ni akoko oun gege bi
gomina ipinle Eko eleyii ti ko gba ona to ye jade.
“Gege bi gomina, mi o saini seeki ri”- Fasola.
Iru ipade yii na jade ninu idahun Rotimi Amaechi, eni to si
ni awon esun kan ti won fi ko o lorun nipa isowo ilu mokumoku. Lara awon idahun
Amaechi niwaju ile igbimo asofin ni , “Emi o gba riba ri laye mi”.
“Gege bi gomina, mi o saini seeki ri”, “Mi o gba riba ri laye
mi”, ti di asa nla bayii eleyii ti opolopo awon eniyan naa ti bere si ni so ohun
ti awon ko se ri.
Arabirin kan ti awon ojulumo re n pe ni mama Bolu ni oun o
sun mo okunrin ri laye oun. Awon omo ile iwe kan ni awon o jiwe wo ri laye
awon. Nigba ti awon kan ni awon o bu tisa leyin ri. Okunrin kan ti oruko re n
je Saheed, to pe ara re ni mekaliiki naa dasi oro naa,“ gege bi mekaliiki, mi o
fowo kan epo enjinni oko ri laye mi”.
0 comments:
Post a Comment