Atelewo ni mo bala |
#OGULUTU #5
Eyin eniyan mi, ohun kan to daju ni wi pe ko si enikeni ti Olorun oba ko fun lebun kan to joju. Eleyii ti o je bi ohun idanimo ti o gbe eni naa han faye ri. Isoro ti opolopo ni ko ju aimo bi won se le sawari awon ebun naa ati bi ebun naa se lme di lilo fun igbega won.
Eyin eniyan mi, ohun kan to daju ni wi pe ko si enikeni ti Olorun oba ko fun lebun kan to joju. Eleyii ti o je bi ohun idanimo ti o gbe eni naa han faye ri. Isoro ti opolopo ni ko ju aimo bi won se le sawari awon ebun naa ati bi ebun naa se lme di lilo fun igbega won.
Ninu ero mi, mo tun gba wa wi pe isoro kan pataki ti awon eniyan tun un koju ni iha ti won ko si orisii ebun kan to jeyo ninu igbe aye won.
Boya ki n ma ti ibi ki yin kaabo si abala Ogulutu, mo si fi asiko yii dupe lowo awon ololufe #IROYINOWURO ti won te atejise sowo si mi.
Bawo ni eniyan se le se akiyesi tabi sawari ebun amutorunwa? Orisiirisii ona ni a le gba se akiyesi iru awon ebun yii ninu igbe aye wa.
Lakoko na, kini awon ohun ti o ma a n wu wa se bi won ko tile ni fun wa ni kobo nidi re? Kini awon ohun ti a ri ti awon kan n se ti a lero wi pe a le se daada ju bee lo?
Kini awon ohun to maa n fun wa ni itara tabi to maa n mu ara wa bumaso nigbogbo igba? Kini awon eniyan maa n so nipa afihan awon ogbon atinuda wa ni awon aye kan? Awon nnkan wo lo maa n ro wa lorun lati se nigbogbo igba?
Ti a ba le dahun awon ibeere yii, pupo ninu awon nnkan to ru wa loju nipa igbe aye wa ni yoo di mimo kedere. Nitori pupo ninu awon nnkan wonyii lo n toka si iru ebun taani ati ohun kan pataki nipa wa.
Opolopo igba ti awon eniyan ba ni awon ko ni ebun kan pataki, ohun to sele ni wi pe won ko ni akiyesi ati se awari iru ebun naa. Nitori wi pe ko si eni kan to wa laye yii ti ko si ohun kan to joju nipa irufe eni bee.
Sugbon nipa aibikita tabi aini akiyesi, awon kan gba wi pe Edua oke ko da ebun kankan mawon.
Eleekeji tun ni wi pe, awon eniyan maa foju kere ebun ti won ni. Afojusun ohun ti awon eniyan maa n wo gege bi ebun pataki ni orin kiko, boolu gbigba, ise tiata ati bee bee lo.
Awon ebun ti won ko ba ti sunmo iru awon ebun bayii ni opo sebi ko wulo tabi ko le gbe awon debi giga. Idi ni yii ti won fi n foju pa iru awon ebun bee re ninu igbe aye won.
Eleeketa to tun se pataki to ye ko ye wa ni wi pe, bi ohun abemi ni ebun je.
Ebun maa n dagba, ebun maa gbon sii, ebun si le ku bakan naa.
Aimoye ebun ti awon eniyan ko se akiyesi ni akoko to ye ki won se bee lo ti ku. Nigba ti awon ebun ti won ko se itoju re bo ti ye ti ku bakan naa latari airi itoju to peye.
Bawo ni eniyan se le sawari iru ebun to ni gan-an ati bi eniyan se le toju ebun re ti o fi digi aloye? Titi ojo mejo taa ma pade, iku o ni pa enikeni ninu wa. Amin
0 comments:
Post a Comment