Smiley face

Aregbesola sedaro Hon. Makinde to doloogbe



Gomina ipinle Osun, Ogbeni Rauf Aregbesola ti ranse ibanikedun si idile Hon Makinde Oladejo Samson to doloogbe lojo Aiku to koja yii, 27/12/15.  Hon Makinde, omo egbe PDP, to je okan lara awon omo ile igbimo asofin ipinle Osun lo jade laye leni odun mejidinlaadota (48) leyin aisan ranpe. 

Iku Hon Makinde, eni ti n soju Aarin-gbungbun Ife nile igbimo asofin, ni gomina Aregbe se alaye re gege bi ajalu nla eleyii ti enikeni ko reti rara ni asiko yii. Ogbeni Aregbe ko sai tun ranse ibanikedun si egbe PDP ati awon eniyan ti Makinde n soju.

"Bi o tile je wi pe ibanuje ni lati padanu odo bi Onarebu Makinde, sugbon ohun to daju niku; gbogbo wa la dagbada iku. Ki Olorun Oba mimo ba wa te si afefe rere," Ogbeni Aregbe fi kun leta ibanikedun re bee.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment