Alaafin ti bere ayeye odun marunlelogoji (45) lori oye pelu idije ese
kikan niluu London
Olayemi Olatilewa
Oba (Dr) Lamidi
Olayiwola Atanda Adeyemi III ti bere ajoyo ayeye odun marunlelogoji (45) to
gori ite awon baba nla baba re lode Oyo. Ayeye yii to ti bere lojo kinni osu
kejila odun yii niluu London, nigba ti asekagba re yoo maa waye laafin Oba
Lamidi lojo kerinla osu kini odun to n bo nibi ti awon oba alaye kaakiri ile
kaaaro-o-ji-i-re yoo ti ma ye baba si pelu aimoye olorin ibile.
Ayeye odun marunlelogoji
yii lo ti bere niluu London lojo kinni osu yii ni kete ti Alaafin wo ilu London
pelu omo re, Omooba Akeem Adeyemi. Aimoye awon omo Yooba pelu awon osise ile
ise asoju ile Naijiria ti won wa niluu Oba ni won tu jade lati se ayesi oba to
je leyin ti Gbadegesin Ladigbolu II goke aja. Lati papako ofurufu ni awon
eniyan ti kowo rin lo si ile Alaafin, ile alarambara to duro ganga soke, eleyii
to kale si Marlin Statford, 2 Millstone Close nigboro ilu London.
Aimoye
orisiirisii eto ti won la kale fun ayeye yii ni won ti n fowo ba lokookan
ejeeji lati ojo kinni osu yii ti omo Adeyemi Adeniran ti wolu obabirin
Elisabeeti. Lara won eto naa ni idiji ese kikan oloresore laaarin Oba Lamidi
ati Larry Ekundayo, ogbontarigi omo Naijiria afeseku-bi-ojo, eni to gbe ami eye
African Boxing Union Welterweigh dani. Leyin ere idije naa ni Larry gbe ami eye
re to gba naa fun Alaafin lati fi saponle re fun ayeye odun marunlelogoji to pe
lori oye.
Bakan naa Oba
Lamidi farahan lori Sky Sport Studio, Ben Television ati Oodua Voice Radio nibi
to ti n ro awon omo Yoruba ti won gbe niluu Oba lati ma so omoluabi won nu.
Bakan naa lo tun ro won lati ma gbagbe orisun won eleyii to je ojulowo ju lo.
Gege bi akosile
itan ilu Oyo se so, ojo kejidinlogun osu kokanla odun 1970 ni Oba Lamidi de ade
oba ilu Oyo nigba ti alase Western Region nigba naa, Colonel Adeyinka Adebayo
fi opa ase le e lowo lati maa dari ilu Oyo. Oba Olayiwola, eni odun
metadinlogorin (77), ni yoo si je oba eleeketalelogoji (43) ti yoo je Alaafin
ilu Oyo.
Gege bi oro
Omooba Akeem Adeyemi, omo Alaafin Oyo, eni to tun je okan lara awon omo ile
igbimo asoju-sofin l'Abuja se so, o ni ayeye odun marunlelogoji oba Lamidi lori
oye eleyii to bere niluu London dabi igba ti eniyan ba woran mariwo lasan.
"Mariwo leleyii, egungun to je baba mariwo ni eyi ti o sele lode Oyo lati
fi ye baba si. Baba je eni kan to lemi ifinsi ati ododo, eleyii si wa lara
awokose rere fun iru awa," Hon Akeem ti gbogbo eniyan mo si Skimeh lo so
bee.
Omooba
Akeem, eni to n duro bi olowo-otun Ikubabayeye niluu London tun fi da awon
eniyan loju wi pe, awon akowe iroyin baba yoo tun maa kede laipe nipa awon eto
ti yoo waye nigba ti Alaafin ba pada wale. O ni aimoye eto lo ti wa nikale,
eleyii ti yoo si maa lo titi ti asekagbe re yoo fi waye lojo kerinla osu kinni
odun ti n bo.
0 comments:
Post a Comment