Lara isoro nla ti ile Naijiria n koju lonii ni isoro airise
awon odo. Isoro kan soso yii si ti bi aimoye isoro kale si orileede wa laifura.
Idaran tilo soke sii, iponju ti ko peteesi si awujo wa, aisan kekere ti di nla
si ago ara elomii latari airowo se itoju ara won botito ati botiye.
Mo ti so ninu awon apileko mi kan seyin wi pe ilu Athens ati
Sparta ni orisun ileewe mooko-mooka. Idi pataki ti won fi se idasile eleyii ni
fun awon eniyan awujo lati le daduro gege bi eda eniyan kan to koju-osuwon lati
le yanju isorokisoro ti won ba koju lai duro de iranlowo enikeni.
Sugbon nigba to ya, awon eniyan ri ileewe gege bi ona lati di
eni atata lawujo. Bi o tile je wi pe iwe kika n soni di eniyan pataki, sugbon
idi pataki ti won fi fi eto eko lele ko ni yii. Awon agbanisise n gba awon ti
won kawe jade latari igbagbo won wi pe, irufe awon eniyan ti won lo si ileewe
koju-osuwon lati yanju isoro ti won ba gbe ka iwaju won. Bakan naa, a ko se
idasile eko mooko-mooka sile fun awon eniyan lati le fi maa wa ise se.
Sugbon laye ode oni, aimoye awon eniyan ni won ri ileewe gege
bi ona kan pataki to le mu won di eniyan pataki lawujo. Bi o tile je wi pe iru
ero bayii n sise ni awon igba kan seyin, sugbon laye ode oni, oro ko ri bee mo.
Aimoye eniyan ni won lo si ileewe to je wi pe won ko rikansekan pelu sabuke owo
won.
Mi o fenu tabuku eko mooko-mooka, bakan naa ni mi o so wi
pe eko kiko o wulo. Ohun ti mo n
gbiyanju lati so ni wi pe pataki ti won fi se idasile eto eko koja bi a se n se
amulo re lode oni. Ero awon eniyan ti won se idasile eko mooko-mooka gaju ohun
ti awa n lo o fun laye ode oni.
Isoro ti a n koju lorileede wa lonii dabi amukun-un ti won ni
eru re wo, oke le n wo, e o wole. Isoro airise gan-an ko ni pataki isoro ti a n
koju bi ko se gbigbagbe orisun ati pataki eko kiko. Eko wa fun ironilagbara ati
iranwo nipa orisii iru eda ti enikookan je lati le daduro gege bi eni to koju-osuwon
lati yanju isorokisoro to ba koju eni
bee lawujo.
Eyi to tunmo si wi pe orisii eko ti Taye ko le ma wulo fun
Kehinde, nitori wi pe eko dalori orisii iseda enikookan. Eleekeji ni wi pe, ilana
tabi agbekale eko gbodo je ohun ti n yanju isoro ti awujo n koju. Nitori pataki
eko tabi idi pataki ti a fi da ile eko sile ni lati le pese awon eniyan ti won
yoo jade nile iwe lati pese ona abayo si isoro ti awujo n koju.
Awon nnkan ti mo salaye soke yii ni ipilese tabi iberepepe
tabi ki n pe ni laarija ti won fi se idasile eko mooko-mooka.
Mo ti salaye saaju bi awon omo akekoo ode oni se n lo si ile
eko giga lati lo ko awon eko to “rewa” latari wi pe ki won le jade lati rise
olowo nla ti yoo so won di eniyan pataki lawujo; lai bikita iru eko to ye ki
won ko gege bi iru iseda eniyan ti won je tabi talenti ti won ni gan-angan.
Abala keji ti n maa menu ba ni orisii agbekale eko aye ode
oni, akoonu eko kiko ati korikuloomu eleyii ti igba ti lo lori re. Isoro to wa
lawujo ni ise iwadii awon akekoo ni ile iwe, to fi je wi pe ti won ba jade,
agbara yoo wa fun won lati le yanju awon isoro naa. Sugbon laye ode oni, isoro
ni awon omo ileewe ti won jade tun je fun awujo. Awon to ye ki won jade maa
yanju isoro ni won tun di isoro si awujo lorun.
Mi o si le fi gbogbo enu ba awon akekoo wi, nitori oju ona ti
mo ti gba koja ni. Aimoye awon eko kiko
ti won gbe siwaju wa nigba ti awa nile iwe ni ko nitunmo si igbe aye ode oni
tabi ti ko wulo nibikibi. Aimoye eko lako to je wi pe oye re gan-an ko ye wa,
ka to wa so wi pe ona ti a o gba lo won lati yanju isoro ti awujo n koju.
Agberu-gbeso
lo mu wa yanju pupo ninu awon idanwo ti
a se. Ti won ba wa ni won se atunse si korikuloomu wa, paali eyin re lasan ni
won paaro, akoonu kan naa lo wa nibe. Awon akoonu ti won ti n lo lati
aye-na-mi-in-nale. Aimoye awon imo eko tuntun lo ye ko ti jeyo ni awon ogba
ileewe wa.
Bakan naa ni awon imo kan wa to ye ki won ti lu pa mole raurau. Sebi
awon agba lonii ogbon odun nii, omugo emii ni. Ona agbekale eko fun awon akekoo
naa tun se pataki to ye ka mojuto ni gidi ati awon eroja ti a n samulo fun eto
eko.
Nje a tile fi igba kan sewadii ohun to mu awon ilu okeere bi China dilu
nla laaarin awon orileede agbaye lojiji? Ohun kan lo damiloju, lori eleyii ni
maa si ti dagbere fose yii: Idagbasoke orileede ko le tayo ipo tabi gbedeke ipo
ti eto eko re wa. Ipo tabi ipele ti eto eko orileede wa naa ni yoo satokun ipo
ti idagbasoke oreleede naa yoo de duro.
0 comments:
Post a Comment