Smiley face

Awon tisa ipinle Kwara taku sori idasesile ti n lo lowo

Gomina Abdulfatah Ahmed

Idasesile awon oluko alakobere to ti bere lati ojo Aje to koja yii nipinle Kwara ni awon egbe oluko ti temu mo o wi pe yoo si ma tesiwaju ayafi ti ijoba ba san gbese owo osu meta ti won je seyin. Ninu oro agbenuso fun Gomina Abdulfatah Ahmed ti ipinle Kwara, Ogbeni Femi Akorede, so wi pe awon ijoba ibile gan-an ni won ru ebi oro naa sori sugbon ipalara idasesile naa ti wa bo sori ipinle Kwara lapapo bayii.

"Ijoba ibile lo je owo ti awon oluko alakobere n beere fun yii. Ijoba ipinle si ti setan lati dide iranlowo sugbon owo ti ijoba apapo n san fun wa lo ha si banki. Eyi lo sokunfa bi oda owo se n da ijoba ipinle lati se awon ohun to ye. A be awon tisa wa wi pe ki won pada senu ise,” Ogbeni Akorede se alaye naa bee.


Okan ninu awon tisa to gba lati ba Olayemi Oniroyin soro lai daruko ara re salaye wi pe, "Mo fi dayin loju wi pe inu ebi la ti n sun la ti n ji ni joojumo aye. Aimoye gbese lati je latari ki ebi ma pawa sile lasan. Owo osu awon oloselu wa ko duro, awon je igbaladun ni joojumo nigba ti awa n jeya lenu bi isu egbodo."


Alaga egbe awon ijoba ibile, Association of Local Government Councils of Nigeria (ALGON), eka ti ipinle Kwara, Alhaji Lateef Okandeji, naa ti rawo ebe si awon tisa lati pada si enu ise won. Ninu oro re, o ni ti eniyan o ba tori epo jesu, o ye ko le tori isu jepo.
“Gbogbo agbara ni ijoba n sa lati ri wi pe gbese osu meta naa di sisan. Gbogbo bi nnkan si se n lo ni awon oloye egbe oluko (NUT) naa mo. Kosi bojuboju ninu awon nnkan to n sele yii. Ko ba si dara ti a ba le jo fi owowewo fun itesiwaju ipinle Kwara,” Alhaji Okandeji se e lalaye bee.

Ninu oro akowe egbe awon oluko, Ola Idris, o ni ohun to daju ni wi pe aja ti ko yo ko le ba eyi to ti yo sere laelae.
"Awon ileri ti ko ni ododo ninu ti awon ijoba n fu wa ti su wa. Awon omo egbe wa ko si le maa fi ebi ko awon omo ni kilaasi. Ko posibu, Ogbeni Ola se lalaye bee.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment