*Won
ni ki INEC ro o loye gege bi asoju awon
*Agba
oloye APC gba Faleke nimoran
Hon. Abiodun Faleke |
Awon
egbe kan ti won kale si agbegbe Ikeja niluu Eko, Ikeja Stakeholders’ Forum,
ISF, ti fesun kan ajo INEC lati kede iroloye Hon. Abiodun Faleke ti n soju ekun
Ikeja nile igbimo asoju-sofin Abuja. Ninu alaye won, won ni eniyan ko ni je oye
Asipa ilu Oyo ko tun maa ba won duye Emir tilu Ilorin Afonja, ko seese.
Ninu
atejade eni ti n se kokari fun ISF, Ogbeni Olanrewaju Osundairo, o ni niwon
igba ti Faleke ti n du ipo gomina ipinle Kogi, o ni ko ye gege bi eni ti o tun
maa soju awon eniyan ti won gbe ni agbegbe Ikeja to wa niluu Eko.
Fun
idi eyi, egbe naa n pe ajo INEC lati kede wi pe, aga ijoko Faleke ti sofo nile
igbimo asoju-sofin gege bi eni ti n soju Ikeja Federal Constituency.
Ogbeni
Faleke to dije gege bi igbakeji gomina oloogbe Abubakar Audu lo si wa lori
ifapajanu eleyii to si tun ko jale lati se igbakeji Alhaji Yahaya Bello ti egbe
fa sile gege bi gomina leyin iku Audu.
Awijare
Faleke naa ni wi pe, oun lo ye ki won o kede gege bi gomina tilu dibo yan leyin
iku oga re, Audu, to waye saaju ki eto
idibo gomina to koja naa to kesejari.
Wayio,
okan ninu awon asaaju egbe All Progressives Congress ti ipinle Kogi, eni to tun
ti fi igba kan je Senato, Ogbeni Adewale Abel, ti ro Faleke lati faramo ohun ti
egbe wi lori oro to wa nile yii. O ni agidi Faleke, Okun ni o pada fi koba
(Okun ni eya awon Yoruba ti won wa ni ipinle Kogi).
"Omo
iya mi ni Faleke, emi o ba ni ko faramo ohun ti egbe wi, ki Okun ma ba padanu
anfaani won ninu isejoba to wa lode yii," Ogbeni Adewale se lalaye bee ni
Lokoja.
Ti e ko ba gbagbe, Faleke ti lo fi iwe ipejo
re sile niwaju ile ejo ti n gbo awuyewuye to ba suye leyin idibo. Bakan naa lo
si ti leri wi pe, oun ko ni yoju sibi eto ibura fun Yahaya Bello gege bi gomina
tuntun nitori ohun ki si se igbakeji re rara.
0 comments:
Post a Comment