Smiley face

Tina ba n joni, ti n jo omo eni…



#ogulutu #13
Owo tabua le mi n fe...
Odun tuntun ti bere. Bi eniyan se ipinnu, bi eniyan gbadura dola, ti eni naa ko ba gbe igbese to ye fun igbe aye irorun, pabo naa ni oro re yoo pada kangun si.  Oro epe ko, otito oro bi isokuso nii ri. Ninu odun tuntun yii, ninu owo ti n wole fun yin, e ri daju wi pe e san owo fun ara yin na ke e to san owo fun enikeni.


O kere tan, ida ogun ninu ogorun (20%) owo ti n wole fun wa gbodo di fifi pamo fun ojo ola wa. Eniyan ti ko ba ti ko iru ogbon bayii, iru eniyan bee n ba won gbe ile aye lasan ni. Ko nii se pelu iru ise ti a n se tabi bi owo ti n wole fun se kere to, iru igbe aye nipa fifi owo pamo gbodo je baraku fun wa. Ko di igba ti eniyan ba  gba owo tabua ko to le se amulo iru ogbon yii. Aseyori yin ko ti bere nigba ti e ba sawon fun baba Kabiru lanloodu, e san owo ori fun ijoba, e san owo ounje fun iya Rebecca oniresi, e sanwo gbandu, e sanwo sokoto, sugbon e wa gbagbe lati san owo fun ara yin; eyin te e sise owo naa gan-an.

E ma si mi gbo, mi o so wi pe ke e maa je gbese tabi ke ma se ojuse yin. Sugbon iwa omugo gbaa ni wi pe e gbagbe lati san owo fun ara yin. Eyin lo ye ko je akoko ti e sanwo fun nikete ti owo ba ti wole fun yin. E le lo si akaunti kan loto nile ifowopamo ti e maa toju iru awon owo bayii si. Owo ti e n fi pamo le kere, sugbon e ma je ko bu omi tutu si yin lokan. E tesiwaju lati maa fi pamo.

E maa gbagbe wi pe bi ojo se n gori ojo la n dagba sii. Awon Yoruba sibo, wo ni ba a nikan agba dani bi ewe laari. Igbese yii le niran fun awon ti won kii se tele, sugbon ti e ba le roju, erin ayo ni o pada gba enu yin. Tita-riro laakola, to ba jina tan ni won mu u soge. Alajetan eniyan won kii nitan rere laye, eniyan ti ko lajeseku ni won gunle sebute ofo.

Olayemi Olatilewa ni oruko mi, igbagbo mi ati ireti mi ni wi pe, lojo kan ni orileede Naijiria, eni ti gun moto mesi-oloye ko ni pe ara re ni olowo mo, nitori teru-tomo ni yoo ni oko ayokele ti won fi se faari nigboro. Nnkan pada bo wa derun fun wa. E ma gbagbe, igbagbo ni orisun ati opin ohun gbogbo. E ku ikale.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment