Olajumoke Orisaguna |
E ku asiko yii, eyin
eniyan mi. Nje eyin tile mo wi pe oju ojo ilu Kenya n fi wakati meji (2hrs)
sare ju tile Naijiria lo? Ti ilu Kenya ba wa laago merin irole, akoko yii ni aago
meji osan yoo lu ni orileede Naijiria. Eleyii ko wi pe ilu Kenya wa niwaju wa tabi
je oga fun ilu Naija, ilu awon eniyan rere. Ohun gbogbo ni i se pelu igba ati
akoko.
Orisiirisii ni iriri aye
eda, aimoye idojuko tabi ipenija ti gbe elomii sanle nigba to ti so awon kan di
alagbara ati olokan lile bi ti jagunjagun. Aimoye aditu aye lo je kedere niwaju
Oluwa oba. Sugbon kini kan lo daju, igba ati akoko eda ko ni ye laelae.
Kini kati pe iyawo osingin
ti oko re ba nile sugbon to je wi pe, leyin odun mewaa (10) to se igbeyawo lo
to finu soyun? Bee si ni enikan an fi joojumo seyun nigba to wa lomidan ti ko
si mosu mesan-an akoko je ninu igbeyawo re.
Emi ti ri eni kawe gboye
leni odun mejilelogun (22) to je wi pe leyin odun marun-un lo to ri taje se.
Bee si ni enikan kawe gboye leni ogbon odun (30) to je wi pe lowo kan to pari
ni Edumare gbo adura re to si rise gidi se.
Orisiirisii ni iriri aye
eda, ohun to gbe enikan subu lo so elomii di akoni. Ika ko dogba, irin ajo eda si
sotooto.
Emi ti ri eni o doga ile ise
nla leni odun marundinlogbon (25) eleyii tiku mulo leni aadota odun (50). Ibe
si ni enikan ti doga ile ise leni aadota odun to si logba titi to fi pe eni
aadorun (90) laye.
Ohun gbogbo n sise pelu
igba ati akoko. Akoko eda, igba eda ko ni koja onikaluku laye. E je ka fi
igbagbo wa sinu Oluwa ka si fi ireti sinu agbara re.
Ore, ojulumo, iyekan, o tile
le je aburo eni lo ti saaju eni, e ma se se ilara enikeni tabi inunibini si
enikeni. E ma se ibaje tabi eta-inu eni Oosa oke ti gbe aga re soke. Akoko ati
igba ti won lo de, tie naa n bo laipe. E mu okan yin le, o daju wi pe ohun
gbogbo n bo wa derun fun yin.
Igbe aye yii kere pupo ju
ki eniyan maa gbe ninu ibanuje lo. E fi ireti sinu igbe aye kan soso te e wa
yii wi pe, nnkan yoo pada bo sipo fun yin.
Eyin e wo orileede ti won
pe ni Switzerland, igi koko (cocoa) kan soso bayii ko wu lori ile won, sibe,
awon ni won se chocolate to dara ju lagbaye.
Kosi anfaani fun yin lati
kuna laye. E dide, e gbagbe isubu ana, e ye e karibonu, e si ma se da enikeni
lebi latari ipo ti e ba ara yin ti ko dara. Ninu igbiyanju ni aseyori wa, e ri
daju wi pe e ko fa seyin tabi duro nigba kankan.
Olayemi Olatilewa ni oruko
mi, o ni le koro, okunkun sile subole lonii. Sugbon o daju wi pe, leyin okunkun
birimubirimu, imole n bo. Adun yungbayungba ni si i keyin ewuro. E ku ikale!
0 comments:
Post a Comment