Aare Muhammadu Buhari |
Orisiirisii apileko ni mo ko lati se afihan asise Goodluck Jonathan ati idi pataki ti o fi ye ki awon eniyan dibo fun Muhammadu Buhari.
Ero mi nigba naa ati ero opolopo awon omo Naijiria ni wi pe, igba Buhari yoo san ju Jonathan lo.
Die lara awon apileko mi nigba naa ni yii:
Awon ohun to n sele lowolowo ninu ijoba Buhari ko tile je ohun to dun mi ju lo, nitori wi pe, ibere kii se onise. A ti wi pe, igbagbo mi ko ye nipa ojo ola rere Naijiria. Mi o kabamo wi pe mo tako Jonathan ninu eto idibo iyansipo re eleekeji. Bi o tile je wi pe, mi o korira Jonathan gege bi olori, asise kan to se, eleyii ti ko je ki n gbadun isejoba re pelu, ko ju iru awon eniyan to ko mora gege bi alajosisepo re lo.
Jonathan le je olori gidi sugbon odaju, ole, ika, eniibi, oloorun, onijekuje, jegudujera, jaguda, gbewiri ni gbogbo awon eniyan to ba sise po. Oun kan naa si faye gba won ju lati se palapala ninu isejoba re.
Eleyii lo mu inu mi dun nigba ti Buhari wole, to si gba a ni opolopo akoko lati yan awon minisita ti won yoo ma ba sise po.
Aimoye awon ojogbon ni won wa ni awon ogba ileewe wa gbogbo ti won pegede. Aimoye awon onwoye ni won wa lawujo wa ti won kun fun ogbon oun laakaye.
Bakan naa ni aimoye odo olopolo pipe po lawujo wa bi yanri eti okun ti awon olori wa le samulo won fun idagbasoke ilu wa. Ero mi ni wi pe, iru awon eniyan yii ni Buhari n wa to fi gba ni aimoye akoko lati ko won jo. Emi sebi awon eniyan oniwa mimo ti enikeni ko gbo oruko won ri ni Baba Daura fe gbiyanju won wo.
Aseyinwa-aseyinbo, iru awon eniyan kan naa ti won ti n fi buredi ko wa lomi obe je lati igba iwase ni baba go slow tun fi se oluranlowo ninu isejoba re. Eleyii je ohun kan to dun mi, mo si ri gege bi asise kan pataki to seese ko fa ifaseyin fun isejoba Buhari.
Ju gbogbo re lo, mo gbadura ki ohun gbogbo tete pada bo sipo, nitori ara n ni gbogbo ara ilu. Awon mekunnu lo si n je eyi to poju ninu iya ti awon olori fi n je Naijiria.
Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Igbagbo mi ko si ye nipa ojo ola Naijiria. Oni le koro, sugbon odaju wi pe adun ni i gbeyin ewuro.
E ku ikale!
0 comments:
Post a Comment