*Awon ika eniyan wo lo wa
nidi isele yii?
*Se agbanipa ni won tabi
awon soja ti won se palapala nigboro?
Oloye Olu Falae |
Oloye Olu Falae ni ori ti
koyo bayii lowo iku ojiji nigba ti awon soja kan ti enikeni ko mo orisun won sadeede
doju ibon ko moto re loju ona Akure si Ilesa.
Baba yii lagbo wi pe o n rin
irinajo lo si Ile-Ife lojo Isegun to koja yii nibi ipade awon Afenifere pelu
Ooni tuntun, Oba Adeyeye Ogunwusi.
“Igba wo ni awon ajinigbe
si ji mi gbe na, nibayii, won tile n lepa lati pami ni.” Olu Falae se alaye fun
awon oniroyin. “Akure ni mo ti n bo,
nigba to ku die ta ma de Ilesa, a ri oko kan niwaju wa. Oko nla van kan naa si
tun wa niwaju tie, niwaju loun. Oko to wa niwaju wa n gbiyanju lati sare ya oko
van to wa niwaju lo un sile, bee gele ni awa naa ba tele. A ti fe koja won ni
mo gbo tako-tako iro ibon lara oko mi.
Oko van yii ko duro, o tun
tena lo ni. Igba ti a de Erin-Ijesa la salaye ohun to sele fun awon olopaa ta a
ri nibe wi pe, oko van nla kan tabon luwa ni ikorita Ile-Oluji". Oloye Olu
Falae tun n se alaye re siwaju pelu edun okan nla nipa awon isele ti n sele si
i.
"Mi o modi ti won fi
jimi gbe titi di akoko yii, mi o modi ti won fi fi olopaa gbemi lodun 1997 ti
won si timi mole fun odun meji gbako. Nibayii, won tile fe pami patapata
ni," Falae se alaye re bee pelu edun okan nla.
Sugbon sa, iwadii ko ti fidi re mule
boya awon agbanipa ni awon soja to yinbon tabi awon soja oniwa palapala ti won
fibon dabira to wu won. Ju gbogbo re lo, iwadii awon olopaa si n tesiwaju lori
isele naa.
0 comments:
Post a Comment