*Won tun ranse si Yar’Adua
lode orun wi pe ko wa salaye
*Ile ejo ti gbe ise to le
fun Aare Buhari lati se
Obasanjo, Yar'dua ati Jonathan |
Kootu ijoba apapo to gaju lo
to kale siluu Eko, Federal High Court, ti fesun kan awon aare ti won ti n je
lati odun 1999 ti ijoba awaarawa tipada latari aise isiro ati afihan okodoro iye
owo ti won ri gba pada lowo awon onijegudujera ile yii, paapa julo, eleyii ti
won ko lasuwon Sani Abacha ati bi won se na awon owo naa.
Ile ejo naa ti wa n pe ijoba
Muhammadu Buhari to wa lode yii lati tanna wadii awon ijoba ti won ti je seyin,
bere lati odo Baba Iyabo, Olusegun Aremu Obasanjo, ijoba oloogbe Umaru Musa Yar’Adua,
ati ijoba Goodluck Jonathan to kogba wole ni kopekope yii.
Idajo yii lo waye lojo Eti
to koja yii lati enu onidajo M.B. Idris, eni to pase eleyii lori ipejo ti ajo
Socio-Economic Rights and Accountability Project (SERAP) gbe si iwaju ile ejo
naa.
Ninu alaye onidajo Idris
lo ti n so wi pe, awon ijoba ateyin wa yii gbodo so iye owo ti won gba lo awon
ti won ko owo ile yii je, iye dukia ti won ri ko lakata awon onijegudujera, a
ti bi ijoba se na awon owo wonyii pelu ohun ti won na le lori.
Wayio, awon onwoye lagbo oselu foju
wo abajade ile ejo naa gege bi ise lile fun ijoba Buhari lati musaloogun. Akoko
na, gege bi alaye won, Buhari ti se ileri fun Jonathan wi pe, oun ko ni yo o
lenu bo ti n wule ko mo. Idaniloju yii lo waye ninu oro apileso akoko Buhari
gege bi aare.
Bi e ba si kiyesi, Buhari ko mu koboko re sun mo Jonathan lati
igba to ti n fina mo awon asebaje lawujo. Nipa ti Ebora tiluu Owu, Obasanjo wa
lara awon igi leyin ogba Buhari ni akoko ipolongo iyansipo re gege bi aare. Se
eniyan a tun ma ge owo to fun ni lounje je bi? Yato si wi pe Yar’Adua
je omo gambari, iku ti mu sagba, ko si ni fe wu Buhari lati tu u lasiri. Bi
nnkan se wa ri yii, oro naa dabi ise oba aigbodo ma je, odo oba to kun ko si se
e rolu. Ki wa ni ki Buhari se lori oro to wa nile yii?
0 comments:
Post a Comment