*”Falala ni awon eniyan yoo ma gbadun ina elentiriki lati ose yii lo” - Lai Muhammed
Latari ina monamona
elentiriki to se monamona lose to koja, eleyii to so gbogbo ilu sinu okunkun
birimubirimu ni ijoba apapo, labe akoso Aare Muhammadu Buhari, ti tori aforijin
lowo gbogbo ara ilu bayii. Sebi moogun-moote, enikan ki i gunyan ewura ko ma
lemo. Ti elebi ba si ti mo ejo re lebi, won ki i pe lori ikunle.
Ikede yii lo jade lati owo
Ogbeni Segun Adeyemi to je amugbalegbe fun fun minisita ti n ri si etigbo, ati
asa, Alaaji Lai Mohammed.
Ogbeni Adeyemi di ebi
isele naa ru awon obayeje kan ti won kolu paipu ti n gbe afefe gaasi, eleyii ti
won on lo lati pin ina elentiriki kari gbogbo ilu. Won ni ninu awon ile agbara
bi merinlelogun (24) ti ile ise monamona ile yii n lo lati fi tan imole fun ara
ilu, metala (13) ni won ri fi sise ninu won lose to koja. Ogbeni Adeyemi ko sai pe fun iranlowo ara ilu lati
fowosowopo nipa gbigbogun ti awon ti won wa isubu orileede yii.
Bakan naa, ninu atejade to
jade lati eka ile ise ijoba eleyii ti Lai Muhammed n dari ni won ti fi da ara
ilu loju wi pe, gbogbo atunse to ye ni ijoba Buhari ti se lati mu nnkan pada
bosipo. Won si tun fi da ara ilu loju wi pe, lati ose yi lo, falala bi omi ojo ni
gbogbo ara ilu yoo maa lo ina elentiriki lo falala.
0 comments:
Post a Comment