*Won yo adari ile igbimo
asofin, won tun da a pada lojo keji.
Awon omo ile igbimo asofin
ipinle Ondo gbimopo yo adari ile,
Arabirin Jumoke Akindele ati igbakeji re, Ogbeni Fatai Olotu bi eni jo yiga kuro
lori aga isakoso lojo Isegun ose to koja yii (08/03/15). Igbese yii lo waye
nigba ti awon omo ile igbimo mejidinlogun (18) ninu awon omo ile merindinlogbon
(26) bu owo lu iwe iyoloye adari ile ati igbakeji re. Ipade ti awon omo ile
igbimo asofin yii se lati yo adari ile loye yii lo waye ni nnkan bi ago mokanla
ale ojo Isegun to koja ni ibugbe awon amofin ipinle naa.
Leyin eyi ni awon omo ile
yii kan naa yan Onarebu Iroju Ogundeji
to wa lati Ijoba Ibile Odigbo gege bi adari ile nigba ti won yan Ayo Arowele
lati Ijoba Ibile Owo gege bi igbakeji re.
Sugbon sa, nigba to di Ojoru, Wesda, to koja yii,
awon omo ile igbimo asofin ti won yo Arabirin Jumoke Akindele ati igbakeji re
loye ni awon ko se bee mo. Sebi ta a ba ni egun baba eni yoo jo, ti ko ba si jo
mo, kosi baba eni to le muni si i. Atejade yii ni Onarebu Olumide George, okan ninu awon omo ile
igbimo asofin to tun je alaga igbimo ti n risi etigbo, (Committee on
Information Chairman) fi sita. Ogbeni George, to je okan lara awon to buwo luwe
iyoloye adari ile igbimo asofin naa, se alaye ohun to sele naa gege bi ede-aiyede
to waye laaarin ebi kan eleyii ti alaafia si ti pada joba.
Lori isele yii kan naa ni akowe
ipolongo fun egbe oselu APC, Omo'ba Abayomi Adesanya, ti bu enu ate lu. Omo'ba
Adesanya ni ohun ti awon omofin naa yoo je ni ko je ki won mo eyi to kan lati
se. Bakan naa lo se apejuwe won gege bi eni ti won fi joye awodi ti ko le
gbadiye.
Sugbon sa, awon oro aheso kan to jeyo
so wi pe, Gomina Olusegun Mimiko lo parowa fun awon asofin tinu n bi naa lati
ma se bi won ti to. Sebi ta a ba ni ka wo didun ifon, eniyan le hora deegun.
Taa ba si ni ti ejo ba se gun to laa se dana re, afaimo ki eniyan ma dana sunle.
0 comments:
Post a Comment