Awon Yooba bo, won tina ko
ba tan laso, eje ki i tan leekanna. Ibi aroko ti si, ibe naa la a fabo si.
Eleyii gele ni se apejuwe aare ile igbimo asofin agba Abuja, Bukola Saraki,
pelu awon esun ti ile ejo tiribuna CCT fi kan an. Igbejo yii lo tun waye lojo
Jimoh ose to koja yii (11/03/16). Gege bi awon asofin ti won duro gege
alatileyin Saraki ti n se bo lateyin , bi ogbon ni won duro ti omo Baba Oloye
ilu Ilorin bi gbogbo won se n kowo rin wo inu kootu tiribuna CCT ni nnkan bi
aago mewaa ku iseju merin aaro ojo Eti to koja yii niluu Abuja.
Saraki, eni odun
metalelaadota (53), ni won fesun aisododo nipa ijewo dukia eni lojulowo fun ajo
Code of Conduct Bureau ati awon esun jegudujera mii nigba to wa nisakoso gege
bi gomina Ipinle Kwara.
Lojo Eti yii kan naa, loju
ona agbawole si kootu tiribuna, awon odo kan ti won je ololufe Saraki gbe
orisiirisii akole dani ti won si n pariwo, “e fi Saraki lorun sile”.
Lopin ohun gbogbo, ile ejo
tun sun igbejo naa siwaju di ojo kejidinlogun osu keta odun yii (18/03/16)
nigba ti Saraki yoo tun ma pada fojuhan lati wa se alaye enu re lekunrere.
0 comments:
Post a Comment