Ni ojo Aje to koja yii
(29/02/15) ni awon ajinigbe kan yawo ileewe Babington Macaulay Junior Seminary
School to kale si agbegbe Ikorodu nipinle Eko ti won si ji awon omo obirin
akekoo meta salo raurau.
Gege bi alaye ti oga agba
ileewe naa, Ven Olaoluwa Adeyemi, se, o ni koto giriwo kan ni awon onisebi naa
gbewole leyin ogba ileewe naa. Leyin ti won wole ni won bere si ni tabon
tau-tau soke ti ina si n fo yo lenu ibon won bi igba ti Sango olukoso ba n
binu. “Orisii ibon igbalode to wa lowo awon amokunseka naa lagbara pupo eleyii
ti ko fun awon osise alaabo ileewe wa ni anfaani lati le doju ija ko won.
Ologini foju jo amotekun ni, nnkan ju nnkan lo,” ogbeni Adeyemi se alaye naa
bee.
Lara iwadii ti OLAYEMI ONIROYIN kojo lojo Isegun (01/03/16) ni wi pe, awon ajinigbe naa ti n beere ogorun
milionu (N100m) lori omo kookan eleyii ti won tun pada din owo naa si ogun
milionu (N20m). Okan ninu awon akoroyin wa gbiyanju lati ba okan ninu awon omo
tabi oluko ileewe naa soro lojo keji isele naa sugbon awon alase ileewe naa ti
paalase fun won lati ma dahun ibeere awon oniroyin kankan.
Ni ojo Wesde (02/03/16), Igbakeji
gomina ipinle Eko to tun je komisanna fun eto eko, Arabirin Idiat Oluranti
Adebule, se abewo si ileewe naa lati ba won kedun isele to waye naa. Bakan naa
lo tun fi da won loju wi pe, ijoba yoo lo gbogbo agbara re lati gba awon omo
naa pada wale.
Oludasile ileewe naa, Dr
Michael Fape, ko sai dupe lowo ijoba ipinle Eko pelu bi awon osise alaabo
ipinle naa se dide ni kanmonkobo nikete ti won fi isele naa to won leti. Gbogbo
agbegbe ileewe naa si ni awon osise alaabo gunle si bayii lati daabo bo emi ati
dukia.
Iru isele to jo iru eleyii
ni eyi to sele ni oru ojo kerinla si ojo keedogun osu kerin odun 2014, nibi ti
awon omobirin orinlugba o din merin (276) ti gbe di ohun awati ni Chibok. Bi o
tile je wi pe lati igba naa ni awon omo ologun ile wa ti n ja raburabu lati ri
awon omo naa ko wa le pada, sibesibe, ori igbiyanju naa ni ijoba apapo wa.
Wayio, komisanna fun
etigbo ati agbekale ilana fun ipinle eko, Steve Ayorinde, kede laaro oni ojo Sande (7/03/16) wi pe awon omo naa ti di gbigba pade wale latari iranwo awon agbofinro ilu Eko
0 comments:
Post a Comment