Sani Abacha |
Ijoba ile Switzerland ti
kede wi pe, ogorun meje ati metalelogun milionu owo dola ilu Amerika ($723m
eleyii to n lo bi N142.43b) ti aare ologun ile Naijiria nigba kan, oloogbe Sani
Abacha ko pamo siluu won ni won ti dapada fun ile Naijiria lati nnkan bi odun
mewaa seyin. Eleyii lo fojuhan ninu iwe
adehun ti ile Naijiria ati Switzerland fowo si lojo kejo osu keta odun yii
(8-03-16).
Yato si eleyii, ijoba ile
Switzerland tun fi kun un wi pe, awon yoo tun da ogorun meta ati okanlelogun
milionu owo dola ($321m eleyii to n lo bi N63.24b) pada laipe yii. Gbogbo
eleyii lo pelu adehun ti orileede mejeeji se eleyii ti Minisita fun eto idajo
ile wa, Abubakar Malami, buwo lu pelu olori eka ile ise ijoba ile Switzerland
ti n ri si oro okeere, Didier Burkhalter.
0 comments:
Post a Comment