Ni awon akoko kan ninu
igbesi aye wa, o ye ki a maa duro lati se asaro ati arojinle nipa awon igbese
wa gbogbo. Se a n tesiwaju ni abi oju kan bi adagun odo la wa? Nitori tomode ba
subu a wowaju, ti agba ba subu a si se bee wo eyin wo. Lori eleyii ni ti maa ki
yin kaabo si abala yii lose yii. Bi mo ba tile ni mi o kowe mo, awon ti won fe
wa, ti won pe mi ko ni je. E ko ni jekoro laelae. Ase.
Ni ibeere pepe odun yii,
mo se laye bi eniyan se le pinnu lati gbaradi fun odun tuntun. Mo so nipa sise
akosile awon ipinnu wa fun odun tuntun ati awon ilana igbese ti o wu wa lati
gbe. Yala eyin fe ko eko kan ni tabi okoowo kan le fe bere.
Elomii le je
igbeyawo tabi idawole kiko ilegbe tara eni. Ohun yowu ko je, a ni lati se
akosile re, a ti ona ti a fe gba ti iru igbese bee yoo fi rorun fun wa. Ohun
kan ti mo tun menuba ni ipinnu wa. Awon nnkan wo la fe yipade? Kini awon atunse
ti e fe se si igbesi aye yin; yala lenu ise wa tabi ninu idile wa? Koda, o le
je laaarin eyin ati Eleda yin ni e ti fe se atunse. Ninu awon apileko mi naa ni
mo ti royin lati bere ohun te ba fe se ni kiakia nitori ti a ba pe lori imi,
esinkeesin ni i ba ni lori re.
Lose yii, mo wa lati wa bi
yin wi pe, ibo ni e ba awon igbese ati ipinnu yin fun odun 2016 ti e se nibere odun
yii de? Se e ti gbagbe ni abi e ti gbe danu sibi kan? Abi eyin ko tile ni
ipinnu rara nibere odun yii? Idi pataki ti akosile fi se pataki ni yii, ni o
fun yin ni o ye boya e n tesiwaju ni abi bi adagun odo le si wa. Akosile iru
nnkan bayii a tun ma fun yin ni koriya nigba ti e ba ri bi e se n tesiwaju.
Odun ko ti pari, anfaani
si po repete fun yin lati mu awon erogba yin se. E ma je ko su yin, e gbiyanju,
e tiraka pelu adura. O daju wi pe, ope loro yin yoo pada jasi.
Bi eyin ko ba si ni ipinnu
kankan fun odun 2016, ko ti pe ju, e si le se ipinnu, ti ohun te pinnu yoo si
bo si fun yin.
Olayemi Olatilewa ni oruko
mi. Ilu to lola ju lagbaye ni mo n gbe. Ilu awon akikanju ati olotito eniyan.
Ki Oluwa bukun Naija, ilu mi.
0 comments:
Post a Comment