Smiley face

Adalabu, eni ogota (60) odun pada sileewe girama

Adalabu ni kilaasi
Awon Yooba bo, won ni igba ta a ba ji naa lowuro eni. Eleyii lo mu ogbeni Adalabu Seribor, eni ogota odun (60) pada si ileewe girama lati lo bere eko kiko.



Baba yii lo woso ile iwe Izon College to wa ni Bomadi-Overside ni ijoba ibile Bomadi nipinle Delta pelu awon omo oniwe keji (JS2) ti won si jo n gba idanilekoo papo ni kilaasi.

"Mo pinnu lati pada si ileewe nitori edun okan nla lo ma n je fun mi lati ma gbe igbe-aye mi gege bi alaimooko-mooka nibi taye laju de yii," Ogbeni Adalabu se alaye ero okan re bee.

Ogbeni Adalabu yii ni ko gbonju mo iya re to fi jade laye, ise ode si ni baba re n se. Igbe aye re lati kekere yii, latari airi oluranlowo, mu ko padanu anfaani lilo si ile eko niberepepe aye re.

"Mo ni igbagbo wi pe oseese ki n di ipo pataki mu lawujo, bawo ni mo se wa fe se lai nimo eko? Se n ma pe awon eniyan lati wa ba mi kowe nigba gbogbo ni? Awon nnkan yii lo mu mi pakitimole, ti mo fi gba ile iwe lo," Adalabu fi kun alaye re.

Ko si orisii ise ti okunrin yii ki i se, bi ko fo gota, salanga kiko tabi ise alabaru. Awon ise yii ti n se leyin ileewe lo si fi n ran ara re ni ileewe.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment