Leyin asiri ajaale Soka n'Ibadan to tu, orisiirisii ajaale ni asiri re ti tu saye ti awon amokunseka si ti fika abamo bonu. Eyi to tun je tuntun lasiko yii ni eyi ti awon olopaa ipinle Ogun tun sawari re ni agbegbe Iyana-Ilogbo to wa ni Sango-Ota nipinle Ogun.
Ile epo akopati kan ti nje Ayokunnu Filling
Station ni owo ti te awon amokunseka meji kan, Babatunde Taofeek ati Hammed Hassan nibi won ti gbe n da aye loro nipa iwa ika owo won.
Orisiirisii eya ara eniyan ni won ba ni ibuba won, oku tutu ati gbigbe. Bakan naa ni won ri bata, baagi ati aso awon eniyan ti won ti ko si panpe wa lara ohun ti won ri ni ogangan ibi isele naa
Yato si eyi, aimoye ohun ija oloro bi ada, obe ati ogun abenugongo ni won ka mo won lowo. Sebi eni ti yoo sowo ale, yoo ni opolopo eni to se e sun gbalaja.
Gege bi iwadii se fi ye wa, awon eniyan meji kan ti awon ika naa ko sinu igbekun sugbon tori koyo ni won kegbajari leyin ti won jajabo. Pelu iranlowo awon ara adugbo ti awon wonyii lo ke ba ni won jijo lo fi oro naa to awon awon olopaa Sango Ota leti.
Alarina fun ile ise olopaa ipinle Ogun, Olumuyiwa Adejobi, jeri si isele naa. Nigba to n fi kun wi pe, awon amokunseka meji ti owo te naa ni won ti gbe won lo si Eleweran niluu Abeokuta.

0 comments:
Post a Comment