Smiley face

Mewaa sele lagbo amuludun

*Lanloodu ti le Wizkid kuro nile re ni Lekki
*Surutu be sile laaarin She Baby ati Kemi Afolabi
*Aye se iranti Hubert Ogunde
*Toyin Aimakhun fe di iyandagbe, o ni oro okunrin ti soun
*Booda Jelili gba kongila olowo tabua

Ayo Balogun (Wizkid)
Gbegede gbina lori ero ayelujara lose to koja nigba ti gbajugbaja onkoroyin ayelujara, Linda Ikeji, kede wi pe, lanloodi Wizkid ti jawe kuro-nile-mi fun omo olorin naa. Gege bi alaye Linda, o ni ile ti Wizkid n gbe ni Lekki yii ni Wizkid so wi pe, oun ra ni nnkan bi odun meloo kan seyin, sugbon ti asiri re tu bayii wi pe bobo naa ya ile naa gbe ni. 

Linda Ikeji
Oro naa ko ba ibi to dun lara baba Boluwatife pelu bo se bere si soko oro alufansa si omobirin oniroyin naa. Koda, o ni okan ninu awon ti n se agbateru oun ti ba sisi naa sun ri ti won si tun gbagbe re sinu yara leyin ti won je dodo re tan.
Kemi Afolabi
Bakan naa ni gobe waye laaarin Kemi Afolabi, omobirin onitia pelu She Baby lose to koja. She Baby to je olorin ati onitiata la gbo wi pe o n ya fiimu kan lowo eleyii to si pe Kemi Afolabi si ibudo ere gege bi akopa. Aseyinwa-aseyinbo lagbo wi pe, She Baby bere si ni pe Kemi Afolabi ni tiifu, ole, barao, gbewiri, o ni Kemi ji oun laso gbe lo. 
She Baby

Kemi ni beeni, o salaye wi pe, owo ile itura ti oun sun lakoko ti oun fi wa loko ere She Baby ni oun beere sugbon ti omoge olorin naa ko lati dapada eleyii lo mu oun ko laso lo. Wahala naa buta soju, ki Saheed Balogun to ba won petu si surutu naa.
Toyin Aimakhu
Ohun ti n sepo ko sora, sebi o ni ohun to de ba kaluku. Toyin Aimakhu ti kede wi pe, oun ko ni pada fe eniyan dudu mo, ayafi oyinbo alawo funfun. Ti oun ko ba si ri okunrin oyinbo fe, a je wi pe iyandagbe loun yoo je titi dojo ogbo nu-un. Eleyii lo waye nigba ti igbeyawo omobirin naa pelu Adeniyi johnson fori lagi. Toyin tun subu sinu ife Seun Egbegbe sugbon ti oro ife naa ko tun pada wooki fun-un.
Wayio, lose to koja yii, owo tabua tu ya sapo Femi Adebayo ti awon eniyan tun mo si booda Jelili oniso pelu bo se towo bowe adehun tuntun pelu ile ise abanikole-abanirale kan gege bi asoju won ni agbegbe Ikeja niluu Eko Oba Akiolu omo Kutere.
Hubert Ogunde
Awon kan lo tun so wi pe, ba a se n ranti awon eni ti mbe laye, ko ye ka gbagbe awon akoni ti mbe lajule orun. Sebi ko si eni ti ko ni ku, ko si eni ti oko baba re ko ni digboro.

Eleyii lo mu awon eniyan se iranti ipile ere tiata Naija, Hubert Ogunde, lose to koja leyin odun merindinlogbon (26) to dara ile. Ogunde, eni to fe iyawo mejila nigba aye re lo jade laye lojo kerin osu kerin odun 1990. Die lara awon ise re ni Aye (1980), Jayesimi (1981), Aropin (1982) Ati Ayanmo eleyii to gbe jade lodun 1988.





Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

1 comments: