Smiley face

Awon alase ti Unilag pa

*Wahala ko sina ko somi lo fa sababi
*Awon akekoo imo isegun faake kori

Awon alase Yunifasiti tilu Eko, Unilag, ti pase titi ileewe naa pa lose to koja yii. Igbese yii lo waye latari ifehonuhan awon akekoo nipa idakureku ina monamona ati omi ti ko si ninu ogba ileewe naa.



Ninu atejade ti awon alase ileewe naa fi sita, won ni lara ohun to mu awon gbe ileewe naa ti tun ni inira owon gogo epo robi eleyii to de ba awon akekoo ti won gba ibugbe sita ileewe naa.


Wayio, awon alase ti fi asiko naa kesi ijoba apapo lati se iranwo lori isoro to wa nile yii nitori ajanaku lo je fun Unilag, eleyii ti ki i seru omode.

Ninu iroyin mii, awon akekoo ti won on ko nipa imo isegun oyinbo naa ko sai pitu owo won nipa ifehonuhan lose to koja yii kan naa. Eleyii lo waye latari ilana tuntun awon alase lati mu adinku ba iye awon akekoo ti yoo ma gba igbega lati inu ogba ileewe naa bo si College of Medicine to je eka ileewe Unilag.

Ojiji ni awon alase fi kun maaki eleyii ti yoo mu awon akekoo pegede lati ni igbega sugbon ti awon akekoo yari wi pe, eleyii kosi ninu ajoso awon nibere eko awon.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment