Smiley face

Leicester City: Eni ti ko gbon lawe n gbo

Awon Yooba bo, won ni, eni ti ko mo ibi egbe re ti la, afaimo ki onitoun ma sare ku. Egbe agbaboolu Leicester City lo wa loke tente bayii lori ate liigi ile Biritiko ti a mo si English Premier League.

Aseyori yii ko sadeede waye, awon onwoye boolu agbaye ni, o seese ko je awure ti egbe agbaboolu naa se lo ti bere si ni je fun won bi idan.



Nibere idije liigi ni awon egbe agbaboolu yii lo gbe Babalawo won wa lati ilu China, eni to ba won se ogun awure naa.

Pupo ninu awon agbaboolu won ni won sin ni gbere lori. Bakan naa ni aimoye agunmu ni won fi po tii gbigbona mu eleyii to so gbogbo won di alagbara ori odan.

Iwaju leye Leicester City n fo bayii nigba ti awon egbe agbaboolu olokiki bi Liverpool, Chelsea, Everton si n fa bo leyin tikotiko bi oko akoyoyo to ti fe gori odo.


Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment