Bi o tile je wi pe odoodun leran ileya n gbe owo lori, sugbon todun yii tun lekenka.
Awon Hausa mola ti won teran gan-an so wi pe, awon eniyan ko wa ra eran odun gege bi won ti n se tele.
Sugbon sa, awon ti Olorun bo lasiri si n ra okookan-ejeeji ninu awon eran ti won pate.
Ni oja Bodija to wa niluu Ibadan, eran agbo to tobi daadaa je nnkan bi egberun lona ogorun naira lo soke (N100, 000 +)
Nigba ti eyi to powole wa sile je nnkan bi egberun lona ogoji si egberun marundinlaadota (40k-45k)
Ni agbegbe Sabo niluu Ibadan, aimoye eran agbo nla ni won ni nibe. Awon agbo ti iwo won ti ka mo eti ti won si tobi daadaa. Eniyan le ri awon eran yi ra laaarin 180k si 250k.
Ni oju ona lati fe wole si ilu Abuja, ileto kan mbe ti won pe ni Zuba, eyin odi ilu Abaju lo wa. Opolopo eran ni won ma ja si Zuba fun awon eniyan Abuja lati wa ba won naja.
Awon eran ti ko fi bee tobi ju ni won ta ni 60k si 65k nigba ti awon eran agbo nla je bi 100k lo soke.
Bakan naa la gbo wi pe aimoye oja to wa ninu ilu Abuja ni ko tile ni eran ti won fe ta fun awon olodun.
Ni agbegbe Ojota ti mo ti kuro bayii, opolopo ojo tile se idiwo fun awon oloja nibe, 135k ni won ta awon agbo ti won leran lara, awon agbo nla ti oju won banileru bi oju kinihun.
Eleyii ti ko tobi ju ni won ta ni 60k si 70k ni oja Ojota
Ni oja Miran to wa ni marose Eko si Abeokuta, agbo kekere ni won ta ni 55k, eleyii to tobi, to yonu kendu bi akeregbe, ti iwo re ka meti bi lawani lemoomu ni won ta ni 180k lo soke.
Abo mi re, eyin naa le je ka gbo iye ti won ta eran ladugbo yin.
0 comments:
Post a Comment