Smiley face

Owo tun te ara meka miran lati Kwara pelu kokeeni

Oladeji Kehinde

Oni agemo ku soju aaro onile, ola agemo ku soju aaro onile, bi oju ko ba ti agemo, o ye koju ti alaaro. Oran yi ti wa n di ojojumo awon ara meka lati Kwara bayii o.

Ni ojoru (Wednesday) to koja yii, iyen ojo kerinlelogun, osu kejo, odun yii, ni ijoba ile Saudi be awon meji lati ipinle Kwara lori gege bi ijiya oogun oloro (cocaine) ti won gbe wo ilu won.

Ni ibamu pelu ofin ile naa, enikeni ti o ba gbe kokeeni wo ile won yoo jebi iku, leyii ti o mu ki awon odanran naa o padanu emi won si ilu oniluu.

Esin iwaju to jin si koto o ko awon ara eyin arinrinajo Meka Medinah odun yii logbon rara.

Eyi ribe bi owo se te arinrinajo Meka miran ni papako ofurufu Abuja, Nnamdi Azikiwe International Airport, pelu isu kokeeni merindinlogorin (76).

Basira Iyabo Binuyo, eni odun marundinlaadota, ni owo osise NDLEA te nigba tiwon n sayewo awon eniyan ti yoo ba oko ofurufu Emirate lo si Saudi Arabia fun isé esin won.

Basira ti o je Omo bibi ibile Irepodun, ni Kwara, ni o gbe awon oogun oloro naa mi bi igba ti eniyan ba mi akasu eba, ti o si ti wa lagado awon NDLEA bayii ti won ni ko ma ya awon ohun ti o ko mi naa ni kiakia.

Basira ti ya merin o din ni ogorin kokeeni bayii, amo awon ti o mu u gba wipe o tan nidi ni amo o si ku niku re, torina ko ma yagbe niso.

Nigba ti o n wi awijare re, Iyabo, eni ti o ni oko pelu omo meta, so wipe ki won soun pele tori owo ti oun ma fi kun oja eso ara (cosmetics) ti oun ta ninu oja Dosunmu l'Eko, ti oja naa yoo si fi gberu si daadaa, ni oun n wa ti o sun oun de idi isé femiwewu naa.

Ninu oro re, o ni enikan ni o so wipe o ma ran oun lo si Meka, amo oun ko ni lo lowo ofo, ni o ba gbe kini ohun fun oun ti oun si ro gbogbo re mi bamubamu.

O ni "mi o koko fe gba lati gbe e amo, o seleri àti fun mi ni milionu naira kan, ni mo ba wo wipe owo naa ma wulo fun mi gidigan ni lo je ki n se amo owo palaba mi si wa segi nigba ti won n ye wa wo. E jo e foriji mi".

Ewe, ni iroyin ti o fara pe e ni a gbo wipe owo te arinrinajo miran ti o ri kokeeni bo inu iho idi re ti o si n gbe lo ile China ki owo to baa ni papako ofurufu tiluu Eko.

Nigba ti won beere lowo e, Okunrin eni odun metadinlogoji, omo ipinle Imo, ti owo ba naa dahun wipe oun mo daju saka wipe pipa ni ijoba ile China ma n pa eni tiwon ba mu pelu oogun oloro amo oun ni igbagbo ti o duro sinsin wipe abere oun ma lo kona okun to di, amo o seni laanu pe ko koja Nigeria ti owo fi ba a.

Alaga aajo NDLEA naa, ajagunfeyinti Muhammad Mustapha Abdalla, fi idunu han si isé takuntakun ti o waye naa. O ni eyi yoo doola emi awon ti o n wu iru iwa yii lowo iku àti wipe yoo sadiku fun ibanilojuje ti iru iwa bayii ma n mu ba ile Nigeria ni awon orile ede agbaye.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment