Smiley face

Adegbodu Twins: Ojo ibi awon omo majẹmu wọle de


Eniyan ti Olorun da ko se farawe. Alagbara ni Olorun ọga ogo, bo se wu u lo n sọla. Talo fẹ bi Oluwa lẹjọ?


Ẹni ti Oluwa n fẹ dabi apata, ẹni to ba binu subu luwọn le fọ yangayanga. Eni ti won ba si koju ija si di dandan ko jẹbi nitori Oluwa mbẹ pẹlu won.

Oni [4-09-16] ni ọjọ ibi Adegbodu Twins, ibeji olorin ọmọ majẹmu.

Iwadii fi ye wa wi pe, ati inu oyun ni asọtẹlẹ Oluwa ti n tẹ le won, bẹẹ si ni aimoye ohun nla lo si wa niwaju eleyii ti yoo pada wasi imuse. Nitori oro Olorun ki i yẹ, Oro Olorun ki i tase. 

Olayemi Oniroyin Agbaye, mo duro lonii ba awon akoni olorin ẹmi igba ti wa yii yọ wi pe, won ku ojo ibi. 

Ni agbara Olorun, gbogbo ire to ku niwaju pata lọwọ yin ma to, gbogbo oke ayọ to ku niwaju pata le ma ri gun pẹlayo. Amin

#HappyBirthday
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment