Kehinde Oladeji
Bi eedi ni tabi asasi, ko seni to le so, amo ohun kan ti o han si gbogbo eeyan ni wipe, tori ife ni okunrin omo ile Turkey yii ti won pe oruko re ni Erdogan Ceren se gbemi ara e ni ojo aje ose ti o koja yii.
Bi awon kan ti n so wipe ife lo ru bo okunrin naa loju ti o fi pinu lati gbemi ara e nigba ti orebinrin e ja a kule ni awon miran n so wipe eedi aye lo di i.
Ojo aje ose ti o koja yii ni Ceren eni odun mejilelogun lo si ori Facebook re ti o si fi edun okan re han lori bi ololufe e ti a ko ti ko tii mo oruko di akoko ti a n ko iroyin yii jo se ja a s'olopon.
Gege bi ohun ti Ceren ko si ori Facebook, o ni " Inu mi baje, okan mi si gbogbe gidigidi.
Amo oro ife wa yoo wa ni akosile, yoo si wa lenu gbogbo eniyan". Bi Ceren ti so bayii tan ni awon ti o je ore re lori Facebook ti bere si ni parowa si ti won si n fi orisirisi oro tu u ninu pe ko ma para e tori obinrin.
Awon kan tile tun ran an leti owe Yoruba kan to so wipe, eni para e nitori obinrin, egbegberun obinrin ma koja lori saare e, amo gbogbo arowa yii pata ni o bo si eyin eti e tori ko pe sigbanaa ni omokunrin yii gbe fidio ara re sori afefe ti opo eniyan si n wo o nibi o se doju ibon ko ara re ti o si so wipe, "ko seni to gbagbo nigba ti mo so wipe ma para mi amo eyin e wo eleyi" bi Ceren ti soro yii tan ni o yin ibon naa sira re nigba aya ti ogun si sise owo re.
Ariwo ibon ni awon obi re gbo ti won fi sa wonu iyara ti omokunrin yii wa amo ki won to gbe e de ileewosan elemii ti gba a.
0 comments:
Post a Comment