Bi eniyan ni oun ko ni soogun ika, eni ti yoo jewo ko ni je. Alaye
yii ni a le fi we bi awon oniroyin kan se kan Toyin Aimakhun leewo nigba
ti won beere ipinnu re nipa oko nini niluu Abuja.
Oro naa dabi eni wi pe o bi oserebirin naa ninu pelu bo se fesi wi pe, ki won maa fi wahala oko nini yo oun lenu.
Isele yii la gbo wi pe o waye niluu Abuja leyin ti Toyin pari ipade re pelu minisita fun eti-gbo ati asa, Alaaji Lai Muhammed.
Toyin binu fi awon oniroyin sori iduro nigba to ko wo inu oko dudu ti ijoba, eka ti ile-ise eti-gbo ati asa.
Se e ko gbagbe wi pe Adeniyi Johnson gan-an ni
ololufee Toyin ni iberepepe? Igba ti edeaiyede be sile laaarin won lo
fo mo Seun Egbegbe.
Sugbon ko tojo ti ibasepo oun ati Ogbeni Egbegbe naa fi fori sanpon.
0 comments:
Post a Comment