Ohun ti a gbo ni wi pe, Buhari lo ranse pe Osinbajo, o si je ohun to ko awon eniyan lominu bi aare se pe iru ipe bee.
Nibi ipade bonkele ti awon mejeeji jo se, nnkan bi wakati kan pere lo fi waye eleyii ti enikeni ko mo ohun ti won jo so.
Adele aare si ko lati ba awon oniroyin soro lori abajade ipade naa.
Sugbon sa, awon kan ni ipade naa ni lati se pataki gan-an ni ki Buhari to ni ayafi ki Osinbajo yoju s'oun.
Kilode ti won ko le fi soro naa lori foonu tabi ori ayelujara ti won yoo ti gbe ma wo ara won loju korokoro?
Ti won ba lo awon ona ibanisoro yii, ko daju wi pe eti keta ko ni gbo ohun ti won jo fe so.
Eyi lo tun mu opo awon eniyan gba wi pe, oro asiri to nipon ni won jo ba ara awon so.
Irin ajo lati Naija si ilu London, laaarin wakati mefa si mejo ni. Irin ajo yii ni Yemi Osinbajo si rin lo rin bo lana yii latari ipade wakati kan pere pelu Buhari.
Aajin, oganjo oru, ni Osinbajo wole de si kaa re to wa nile ijoba, Aso Rock, Abuja.
Ti e ko ba gbagbe, laipe yii naa ni aya Buhari, Aisha Buhari, se abewo si oko re nibi ti awon eebo alawo funfun ti gbe n se itoju re.
Arabirin aya aare si fi da awon eniyan loju wi pe, ara baba ti n mokun diedie.
Lara awon nnkan ti aya aare tun so ni bi o se n fi owe soro nipa awon kan ti won ko gbadura ki Buhari mori dele pada.
O ni awon kan an gbadura iku fun aare ninu isejoba Buhari ki won le maa se yalayolo ti Buhari ba lo tan.
Sugbon o se idaniloju wi pe, gbogbo won ni oju yoo ti nigba ti Sai Baba ba de pelu owo agbara. O si tun fi kun un wi pe gbogbo won ni won yoo yo danu bi igba ti won yo jiga.
O seese ki eleyii wa lara asiri ti Buhari fe fi pamo sowo Osinbajo. Sugbon enikeni ko le se idaniloju eleyii.
Lati igba ti Buhari ti lo siluu London, isejoba ko rorun fun Osinbajo pelu bi awon kan se gbimopo labenu ti won si n gbogun ti baba kekere.
Ju gbogbo re lo, ireti ati adura nikan lo ku fun wa, a si n gbadura wi pe, laipe ni aare yoo seri pada wa sile.
0 comments:
Post a Comment