Kí n má parọ́ asiko kò ti to fún Nàìjíríà láti bo lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú amunisin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òye àwọn ènìyàn tí ń lá ju ti ateyinwa lọ, sibẹsibẹ a kò ti débẹ̀.
1.Ilànà eto iyansipo àti idije fún ipò faye gba jẹgúdújerá. Lati gba fọ́ọ̀mù idije lábé ẹgbẹ́ òṣèlú fún ipò aare, okere ju, milionu mewaa owo ni ẹni náà yóò san eléyìí tí kò dájú wí pé yóò padà soju ẹgbẹ́ naa.
A kò ti sọ ipolongo eléyìí to je ise gan-angan. Enikan tile so wi pe ti ènìyàn yóò bá díje fu aare, iyen àwọn ènìyàn tí wọ́n setan, eni naa gbogbo ṣètò ọgbọ́n bilionu pamo.
2.Lopo igba àwọn ará ilú a sebi àwon ni awon yan adari. Ìró ni. Awon Borokini alenulọrọ ni won yan fun wa. Mi ò so nipa èrú ṣíṣe nipa eto ìdìbò. Ohun ti mo n so ni yii, ki awon ara ilu to dibo fún Obasanjo ni 1999, awon kan ni won jókòó tí wọ́n sì sọ wí pé Obasanjo la fẹ. Bakan naa ni won se nipa Olú Falae. Èyí yòówù tí a lè dibo fun nínú àwọn méjèèjì, kí ṣe ìfẹ́ ọkàn wa, ero àwọn kan ni.Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ seri ni ijoba ìpínlẹ̀ ati ìbílè.
3. Eto oro aje wá to dórí kodò je ko nira láti yan olórí gidi. Ebi ń pa awon ènìyàn, eniyan ti ebi ń pa tí wọ́n fun lẹ́gbẹ́run márùn-ún kò wá dibo, se ko ni di? Bẹ́ẹ̀ ni ilu òkèèrè, àwọn ará ìlú ni won dawo fún ẹni wọn ba fẹ ko díje.
4. Ènìyàn rere kò lọ dije ipò kò wọlé ní Nàìjíríà lai ma ni atileyin àwọn jẹgúdújerá, ojelu, ìkà, àti odaju olóṣèlú. Se e ranti wi pe Fela, Fawehinmi tí dije rí, bakan naa ni ilakaka MKO padà ja sofo náà ni.
Ìró laye n fe, òtítọ́ ni wi pe olùgbàlà wá kò sì nítòsí.
0 comments:
Post a Comment